Ìgbésí Ayé Kristiẹni

Àwọn agbára méjì ló wà ní ayé yí, tí wọn fẹ́ láti ṣẹ́gun àti láti jọba lórí àwọn ọmọ ènìyàn. Ọkàn nínú wọn jẹ́ Ìjọba ti Ọlọ́run pẹ̀lú Kristi Olúwa tó ń darí rẹ. Gbogbo wa lo wá lábẹ́ ìtẹríba fún ọkàn nínú àwọn agbára ńlá yìí. Olúkúlùkù wa lo ni olórí tí ṣe ọkàn nínú àwọn Ọ̀gà alágbára wọ̀nyí. Jésù wípé: “kò sí ẹni tí ó lè sin Olúwa méjì” (Matt. 6:24), ju bẹ́ẹ̀ lọ, “Ẹnití kò bá wà pẹ̀lú mi, ó ńṣe òdì sí mi, ẹni tí kò bá sí bá mi kò pọ̀, ó nfọ́nka.” (Matt. 12:30). Báyìí ni gbogbo wa, là jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ lábẹ́ ọ̀kan tàbí èkejì nínú wọn. Àwọn méjèèjì ló ní ìtara sì wa láti jẹ olusin wọn. Àwọn ẹ̀bùn àti orisirisi ìlérí tí ọ̀ga ìjọba ayé yìí ṣe fún sìnsin wá dabi pé wọ́n wuni, wọ́n sì pọ̀; díẹ̀ nínú wọn ni ìgbésí ayé tó l'ádùn láì ni ìṣòro pẹ̀lú fàájì púpọ̀, lílọ sì íjó, wíwòran atafo-ojú (cinema), tẹ́tẹ́, títa ayò ìwé pẹlẹbẹ (card), lílọ síbi ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti sí ibi tí wọ́n ti nse àsè. Èṣù gbìyànjú láti fi gbogbo nkàn tí ó bá ń fẹ́ láti ni fún ọ, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, kò ṣe ìlérí fún ọ ní ti ẹ̀yìn ayé yìí, kò sọ fún ọ nípa ọjọ́ ẹ̀san ńlá èyí tí ó mbọ̀ wá tàbí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ tí wọ́n dúró de èrè wọn ti ìṣe iná-àjóòkú tí a ti pèsè sílè fún èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Matt. 25:40-46). Kò tilẹ̀ rán ọ létí pé òun ni ẹni tí ó wà nìdí gbogbo ẹ̀sẹ̀, ìtìjú, ìmúlẹ̀-mófo, ìbànúnjẹ́ àti ikú pãpã tìkára rẹ̀ tó wà nínú ayé yìí. Ăh, irú ọ̀gá báyìí!

11 Ṣẹ́r 2025 in  Ìgbésí Ayé Kristiẹni 5 minutes