“Tani yio gun ori oke Oluwa lo? Tabi tani yio duro ni ibi-mimo re? Eniti o li owo mimo, ati aiya funfun: eniti ko gbe okan re soke so asan, ti ko si bura etan.” (Orin Dafidi 24:3-4). Nje Iwo a lee duro niwaju Olorun ni idajo pelu Iwo mimo ati aya funfun bi? Melo ninu wa lo lee so pe mo ni owo mimo ati aya funfun? Iseda eniyan ko lee duro niwaju Olorun. Olorun nilo lati se iranlowo pelu ona fun iwenimo. Nitorinaa, O ran Jesu lati rawapada ati lati we a won owo ati okan wa mo.
Kíni Ìbẹ̀rù? Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ìbẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la Ìbẹ̀rù Ìjákulẹ̀/Ìkùnà Ìbẹ̀rù Ìjìyà Ìbẹ̀rù Ikú.
Àwọn agbára méjì ló wà ní ayé yí, tí wọn fẹ́ láti ṣẹ́gun àti láti jọba lórí àwọn ọmọ ènìyàn. Ọkàn nínú wọn jẹ́ Ìjọba ti Ọlọ́run pẹ̀lú Kristi Olúwa tó ń darí rẹ. Gbogbo wa lo wá lábẹ́ ìtẹríba fún ọkàn nínú àwọn agbára ńlá yìí. Olúkúlùkù wa lo ni olórí tí ṣe ọkàn nínú àwọn Ọ̀gà alágbára wọ̀nyí. Jésù wípé: “kò sí ẹni tí ó lè sin Olúwa méjì” (Matt. 6:24), ju bẹ́ẹ̀ lọ, “Ẹnití kò bá wà pẹ̀lú mi, ó ńṣe òdì sí mi, ẹni tí kò bá sí bá mi kò pọ̀, ó nfọ́nka.” (Matt. 12:30). Báyìí ni gbogbo wa, là jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ lábẹ́ ọ̀kan tàbí èkejì nínú wọn. Àwọn méjèèjì ló ní ìtara sì wa láti jẹ olusin wọn. Àwọn ẹ̀bùn àti orisirisi ìlérí tí ọ̀ga ìjọba ayé yìí ṣe fún sìnsin wá dabi pé wọ́n wuni, wọ́n sì pọ̀; díẹ̀ nínú wọn ni ìgbésí ayé tó l'ádùn láì ni ìṣòro pẹ̀lú fàájì púpọ̀, lílọ sì íjó, wíwòran atafo-ojú (cinema), tẹ́tẹ́, títa ayò ìwé pẹlẹbẹ (card), lílọ síbi ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti sí ibi tí wọ́n ti nse àsè. Èṣù gbìyànjú láti fi gbogbo nkàn tí ó bá ń fẹ́ láti ni fún ọ, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, kò ṣe ìlérí fún ọ ní ti ẹ̀yìn ayé yìí, kò sọ fún ọ nípa ọjọ́ ẹ̀san ńlá èyí tí ó mbọ̀ wá tàbí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ tí wọ́n dúró de èrè wọn ti ìṣe iná-àjóòkú tí a ti pèsè sílè fún èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Matt. 25:40-46). Kò tilẹ̀ rán ọ létí pé òun ni ẹni tí ó wà nìdí gbogbo ẹ̀sẹ̀, ìtìjú, ìmúlẹ̀-mófo, ìbànúnjẹ́ àti ikú pãpã tìkára rẹ̀ tó wà nínú ayé yìí. Ăh, irú ọ̀gá báyìí!
Olúkúlùkù ènìyàn ló ńsin ohun kan. Àwọn míràn ǹsin ohun tí a fi ojú rí, igi, oòrùn, omi, òṣùpá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn míràn nsin ènìyàn, àwọn mìíràn nsin ère tàbí àwòrán, àwọn míràn si nsin ara àwọn tìkára wọn. Wọ́n máa ńfi isẹ́ ìsìn wọn sí òrìṣà wọn hàn ní onírúurú ọ̀nà. Bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yii ti nsin àwọn òrìṣà wọ́n yí tó, ọkàn wọn kún fún ìpòngbẹ ati ẹkún. Ìwọ̀nba ìtura díè ni àwọn wọ̀nyí ńrí fún igbe ọkàn won, ati ìgboyà kékeré láti kọjú ọjọ́ ọ̀la. Sí ìjákulẹ̀ wọn, bí ọjọ́ àná ati ọ̀la wọn máa ń rírí. Àwọn ohun tí wọn ńsìn kò leè di ìsófo nínú ìgbé ayé wọn.