Jesu sọ fun wa pe awọn ilẹkun ogo ti mọ wa, afi bi aba tun wa bi. Nitorina a bere lọwọ rẹ: ọrẹ, njẹ a ti tun ọ bi? Iwọ ọmọ Ijọ, njẹ a ti tun ọ bi? Bi bẹkọ iwọ ti sọnu. Nitori Jesu wipe, “Bikosepe a tun enia bi on ko le ri ijọba Ọlọrun” Johannu 3:3. Dajudaju ko si ẹniti o fẹ ku sinu ẹsẹ tabi ti o fẹ segbe; nitorina, a nilati tun ọ bi.
Sugbọn iwọ le bere pe, kini itumọ atunbi? Lọna ekini a o sọ ohun ti atunbi ki ise fun ọ. Itẹbọmi ki ise atunbi; nitoripe awọn miran se itẹbomi sibẹ ti nwọn ko si ni atunbi (Ise Apos. 8:18-25). Ki işe didarapọ mọ Ijọ, nitori ọpọ ni o yọ wọ inu Ijọ laimọ (Galatia 2:4). Atunbi kọ ni jijẹ Onjẹ Alẹ Oluwa: nitori ọpọ ni o njẹ laiyẹ ti nwọn si ngba ẹbi sori ara wọn (I Kọrinti 11:29). Atunbi ki işẹ gbigbiyanju lati se atunse tabi lati gbiyanju lati gbe igbe-aiye ti o dara ju ti atẹhin wa, “…Mo wi fun nyin, enia pupọ ni yio wa ọna ati wọ ọ, nwọn ki yio si le wọle” (Luku 13:24). Ki işe adura gbigba ni atunbi, nitori Jesu wipe, “Awọn enia wọnyi nfi ẹnu wọn sunmọn Mi nwọn si nfi ete wọn bọla fun Mi: Sugbọn ọkan wọn jina si Mi” (Matteu 15:8).
A le wipe, “Bi mo ba sa gbogbo ipa mi, ti mo si ntọrẹ anu, ti mo si mbẹ awọn alaisan wo, ti mo sin se rere lojojumọ bi mo ti le se mọ, nigbana a ti tun mi bi.” Bẹkọ, a ko le jẹ ohun ti a ki ise; “Nitori ero ti ara, ọta ni si Ọlọrun: Nitori ki tẹriba fun ofin Ọlọrun on ko tilẹ le se e” (Romu 8:7). A nilati ni iyipada ọkan. Nitori Ọlọrun sọ lati ẹnu awọn woli pe “Emi o fi ọkan titun fun nyin pẹlu ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkan okuta kuro ninu nyin, emi o si fi ọkan ẹran fun nyin-“ (Ezekiel 36:26).
Nitorina a bere pe, kini itumọ atunbi yi? Kini idi ti a fi npe e ni bibi? Bawo ni, ati nigbawo ni a le ri atunbi gba? Jesu wipe, “Eyiti a bi nipa ti ara, ara ni” (Johannu 3:6). Ẹni bi ọmọ ni ọmọ njọ. Nigbati a ba bi ọmọ, ẹda titun ti ko ti wa ri yio wa, on yio si di enia, sugbọn ẹlẹran ara ni. Bakanna ni nigbati a ba tun wa bi, iye titun ninu Jesu Krist yio ti ọdọ Ẹmi de sinu wa. Eyi ni ohun ti ko ti wa ri, a le fi we ibi nipa ti ara. Nitorina, a npe eyi ni atunbi-igbe-aiye-titun ninu Krist Jesu ti yio wa titi lai; nitori Jesu wipe, “Ẹnikẹni ti o mbẹ laaye, ti o si gba mi gbọ, ki yio ku lailai” (Johannu 11:26). Njẹ a ki nwi pẹlu iyanu gẹgẹni Nikodemu pe, “Nkan wọnyi yio ti se le re bẹ”? (Johannu 3:9).
A tun nilati se akiyesi ọrọ ti Jesu sọ wipe “Enia ni eyi soro fun sugbọn ohun gbogbo ni sise fun Ọlọrun.” Nitori bi a ba wa siwaju Ọlọrun gẹgẹbi ẹniti o sọnu ti o nru ajaga, ti a mọ ara wa ni ẹlẹsẹ, alaiyẹ, olufẹ ohun ti ara, laini alafia ti ọkan, ti a nwa isimi ati alafia, ninu ibanujẹ, ti a si kigbe gẹgẹbi ti olori tubu ni pe, “Kini ki emi ki o se ki mba le la?” Nigbana ni Paulu wipe, “Gba Jesu Kristi Oluwa gbọ” Ẹ jẹki a se akiyesi pe ọgbọn ti pin fun ọkunrin yi. A le tumọ ibere rẹ si pe, “Emi yio se ohunko–hun ki a ba le gba mi la.” Eyi ni ijọwọ ara-ẹni-lọwọ patapata.
Ọlọrun ẹniti nwo ọkan ri wipe ki işe pe iwọ yio sa wipe, “Oluwa, Oluwa,” nikan ti iwọ ki yio se ohun ti O wi, sugbọn iwọ yio se igbọran ki iwọ si wa laaye fun U, Ọlọrun nwa sọdọ enia nipa agbara Ẹmi-Mimọ, A si da aiya titun sinu rẹ. (Orin Dafidi 51:10). Bayi ni a tun ọ bi, o si di ẹda titun ninu Jesu Kristi nipa igbagbọ ninu Rẹ. (II Korinti 5:17).
Sugbọn nigbawo ni mo le reti pe ki a tun mi bi? Ọlọrun wipe, nipa Ẹmi-Mimọ “–loni bi ẹnyin ba gbo ohun Rẹ” (Heberu 3:7). Itumọ eyi nipe, a le gbọ ipe Rẹ nigbakigba, nibikibi, ti a ba sa ti gbọ ipe Rẹ pe, wa. A le wa ki asi tun wa bi nipa Ẹmi, nipa bẹ, ki a si di ọmọ Ọlọrun, arole Ọlọrun ati ajumọ jogun pẹlu Kristi (Romu 8:14-17).
Bawo ni yio ti pẹ to, ki ha se pe ngo ma dagba sinu atunbi na diẹdiẹ ni? Ki se bẹ rara, iwọ Olukawe wa ọwọn, ninu Ijọba Ọlọrun ti a bi wa si; ti mu wa di arole ati ọmọ Ọlọrun, eyi si le sẹlẹ ni iseju ti a ba ti fi gbogbo rẹ fun Jesu, ti a si wa sọdọ Rẹ fun anu ati idariji.
Ni ipari: bawo ni mo ti sele mọ pe a ti tun mi bi? Paulu kọ wa ninu II Korinth 13:5 pe, Ẹ ma wadi ara nyin, bi ẹnyin ba wa ninu igbagbọ; ẹ ma dan ara nyin wo. Tabi ẹnyin tikara nyin ko mọ ara nyin pe Jesu Kristi wa ninu nyin? Afi ti ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanu.” Nitorina ni didan ẹmi aini atunbi wo, Bibeli kọ ni pe, nwọn ku ninu ẹsẹ, wọn sọnu a da wọn lẹjọ, nwọn ni ẹri ọkan buburu, nwọn nlepa ohun ti nse ti ara, nwọn ko ni ireti, nwọn jẹ alaigbọran, nwọn wa laini Ọlọrun ni aiye yi, nwọn si jẹ ọmọ Esu. Lodi si awọn nkan wọnyi, onigbagbọ ti a ti tunbi di ọmọ Ọlọrun. O wa laaye ninu Jesu, a gba a la, a ko da lẹjọ mọ, o ni ẹri ọkan rere, o nlepa ohun ti ẹmi, o kun fun Ẹmi-Mimọ, ati igbagbọ, pẹlu ireti iye ainipẹkun. A pa ẹsẹ wọn rẹ, a si nu u nu nipa ẹjẹ Jesu. Ọkan wọn kun fun ifẹ ati alaafia ti o ju gbogbo-imọ lọ, wọn ni ifẹ ati itara, nwọn si ni agbara lati se ifẹ ti Oluwa. Nwọn ni ireti tayọ inu boji, nwọn si ni ireti ninu ileri pe, “–Emi o tun pada wa, Emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbe wa, ki ẹnyin le wa nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3). Nitorinaa a bere lọwọ rẹ pe, njẹ o sese ki ẹnikẹni ni iyi pada wọnyi ki on ma mọ? Eyi fẹrẹ ma sese, Nitoripe, “Ẹmi tikararẹ li o mba ẹmi wa jẹri pe ọmọ Ọlọrun li awa ise” (Romu 8:16).
Olukawe wa ọwọn, bi iwọ ko ba ni ifẹ si iru iriri yi ati iye ninu ọkan rẹ, mase simi gẹlẹtẹ, nitoripe iwọ nfi Ọlọrun ati ẹmi ara rẹ sire. A NILATI TUN NYIN BI.