Olúkúlùkù ènìyàn ló ńsin ohun kan. Àwọn míràn ǹsin ohun tí a fi ojú rí, igi, oòrùn, omi, òṣùpá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn míràn nsin ènìyàn, àwọn mìíràn nsin ère tàbí àwòrán, àwọn míràn si nsin ara àwọn tìkára wọn. Wọ́n máa ńfi isẹ́ ìsìn wọn sí òrìṣà wọn hàn ní onírúurú ọ̀nà. Bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yii ti nsin àwọn òrìṣà wọ́n yí tó, ọkàn wọn kún fún ìpòngbẹ ati ẹkún. Ìwọ̀nba ìtura díè ni àwọn wọ̀nyí ńrí fún igbe ọkàn won, ati ìgboyà kékeré láti kọjú ọjọ́ ọ̀la. Sí ìjákulẹ̀ wọn, bí ọjọ́ àná ati ọ̀la wọn máa ń rírí. Àwọn ohun tí wọn ńsìn kò leè di ìsófo nínú ìgbé ayé wọn.
Tani ìwọ ń sìn? Níbo ni ọlọ́run tìrẹ ǹgbé? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ wà láàyè? Kíni ohun tí o se fún ọ lónìí? Ǹjẹ́ o baa sọ̀rọ̀ lónìí? Ǹjẹ́ o fi ìdáhùn fún igbe ọkàn rẹ bí? Kíni ìwọ gbàgbọ́?
Jẹ́ kí nse àfihàn Ọlọ́run òtítọ́ kan ti o ti ṣẹ́gun Sátánì , ọ̀tá wa ti o ga jù lọ . Òun ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá, ti o fi kìkì ọ̀rọ̀ ni kan da ohun gbogbo. Bíbélì mímọ́ yíò sọ fún ọ nípa Ọlọ́run ọ̀run yii ti o da ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀.
Ka ìwé Gẹ́nẹ́sísì orí kíní àti èkejì. Òun ni Ọlọ́run ayérayé. Kò ní ìbẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ni òpin. Ọkàn náà ni lánàá, lónìí ati títí ayé àìnípẹ̀kun. Òun ni Ẹlẹ́dàá, Olùtọ́jú ati Olùpamọ́ ohun gbogbo (Ìse Àwọn Àpọ́sítélì 17:22-34).
Ọlọ́run yii ti ǹgbé nínú àwọn ọ̀run ní inú dídùn sí ọ gẹ́gẹ́ bi ènìyàn. Ó rí ọ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. O nífẹ̀ẹ́, o si ǹbójú to ọ. Ó sì tún fẹ́ láti se ju ọ̀rẹ́ lọ. Ó ti rán Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ Olùgbàlà rẹ. Ó fẹ máa bá ọ gbé, ati ju bẹ́ẹ̀ lọ lati fi inú rẹ se ibùgbé. Ó sọ wípé, “Ẹ máa gbé inú mi, èmi o si máa gbé inú nyín.”(Johannu 15:4).
Bí Òun kò bá ǹgbé inú ọkàn rẹ, taló ń gbé ibẹ̀? Ní wíwo àyíká wa, a lè ri pe Sátánì lo ń ṣàkóso , tó si ti ba ìgbé aye ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́. Òun náà ni ọ̀gá inú àwọn ọkàn wọ̀nyí. Ó d’àbá àwọn ìwà ibi wọ̀nyí fun wọn bí irọ́ pípa, olè jíjà, ṣíṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, rírẹ́nijẹ, ìgbẹ̀san ati gbígbé ara ẹni ga. Bi Sátánì ba ǹgbé inú ọkàn rẹ , yíò mu ìfẹ́ àwọn ẹ̀sẹ̀ yìí máa fà si ọkàn rẹ láti máa gbé inú wọn àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, ìwọ ki yíò a tọ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run wá tí o fi Ọmọ Re kansoso, Jésù Krístì, tó kú fún ṣẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ti gbogbo àgbáyé (Johannu 3:16). Ìwọ
ḿbéèrè pe, “Báwo ni èyí se leè jẹ́ òtítọ́? Báwo ni Ẹni Náà, ti o ga to bẹ́ẹ̀, tó ni gbogbo agbára àti Olódùmarè le máa gbénú ọkàn mi?” (Isaiah 57:15).
Bí o bá ńsàárẹ́, ti ẹ̀ṣẹ̀ si sú ọ, ìwọ kò se képe Ọlọ́run, ki o si ronúpìwàdà. Nípa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ati ètùtù ẹ̀jẹ̀ Krístì, a o dárí ẹ̀ṣẹ̀ re jì ó, ìwọ yíò si di ẹ̀dá tuntun. Nígbà tí Sátánì ba gbé ìdánwò dé, ìwọ yíò ní ìmọ̀lára Ọlọ́run Alágbára nínú re. Yíò fún ọ ni ìtọ́ni yíò si kọ́ọ ni ohun gbogbo pẹ̀lú. (Johannu 14:26).
Nínú ìwé Johannu 10:10, Jésù se ìlérí ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀, Òun pẹ̀lú si ni agbára láti fún o. Níwọ̀n bi o ba je olótìítọ́ ati olùgbọ́ran, ẹ̀bùn yíò máa je tire títí. “Bí ẹ̀nyin ba fẹ ti e si gbọ́ran, ẹ o jẹ ire ilẹ̀ náà:”(Isaiah 1:19). Kò si Ọlọ́run míràn ti o ga bi irú èyí. Ǹjẹ bi èyí ba bá ọkàn re sọ̀rọ̀, o le fẹ ka ìwé ìléwọ́ “A ni láti tún yín bí”. Ìwé yi ati àwọn míràn wa ni àdírẹ́sì ìsàlẹ̀ yìí.