“Tani yio gun ori oke Oluwa lo? Tabi tani yio duro ni ibi-mimo re? Eniti o li owo mimo, ati aiya funfun: eniti ko gbe okan re soke so asan, ti ko si bura etan.” (Orin Dafidi 24:3-4). Nje Iwo a lee duro niwaju Olorun ni idajo pelu Iwo mimo ati aya funfun bi?
Melo ninu wa lo lee so pe mo ni owo mimo ati aya funfun? Iseda eniyan ko lee duro niwaju Olorun. Olorun nilo lati se iranlowo pelu ona fun iwenimo. Nitorinaa, O ran Jesu lati rawapada ati lati we a won owo ati okan wa mo.
Nje o tile woye ri, bi igbe aye e re ti ri loju Olorun? Jesu so fun wa, “Gbogbo oro were ti eniyan nso, won o jihin re li ojo Idajo.” (Mat. 24:36). Niwon bi awa o ti jiyin gbogbo oro were ti a ba so, o daju pe awon akosile kan ti wa. Bibeli so nipa awon akosile wonyi ninu iwe Ifihan 20:12, “Mo si ri awon oku, ati ewe ati agba, neon duro niwaju ite; a si si awon iwe sile; a si si awon iwe miran kan sile ti ise iwe iye: a si se idajo fun awon oku lati inu ohun ti a ti ko sinu awon iwe na, gege bi ise won.”
Joshua Harris, odokunrin lati Maryland, USA, o nlo akoko die in Puerto-Rico. Ni oru ojo kan, o la
ala. O gba pe Olorun lo fi ala yii han oun gege bi itoni fun Igbe aye aisododo. Ala yii ran an letii agbara ti nyi igbesi aye eni pada ti wa ninu Jesu Kristi ati eje Re. A o fe so fun yin.
* * * * *
(IYARA NAA)
Ni ibi kan naa, laarin wiwa laaye ati l'oju ala, mo ba ara mi ni inu iyara kan. Ko tile si ohun afiyesi pataki ju ara ogiri kan ti o ni awon iwe itokasi pelebe (files / dossier) lara. Won dabi awon to maa nwa ni ibi isewelojo si (libraries / bibliothèque) ti a ko leselese pelu oruko onkowe tabi akole iwe won ni tele tele. Sugbon awon faili(dossier) wonyi kun ara ogiri yi lati isale titi de oke aja iyara naa to dabii pe ko lopin lotun ati losi, pelu akole lorisirisi. Bi mo ti nsunmo ogiri to ni awon faili(dossier) wonyi, eleyi to koko wo oju mi ni akole yii pe “Awon omidan ti mo ti n'ife si ri”. Mo sii, mo si bere sii wo awon iwe pelebe inu re, lojukan naa, eru ba mi, mo yara paade, nitori ti mo da awon to ni oruko to wa ninu iwe yii mo.
Leyin eyi, bi enkan ko tile so fun mi, mo ti mo ibi ti mo wa. Iyara alaini emi yi kun fun akosile pipeye nipa igbesi aye mi, nibe isee mi gbogbo ati akoko won, yala kekere tabi nla ni kikun ti iye mi ko lee gbe. Pelu iyanu on aibale okan ati irora okan kun okan mi bi ti nwo inu iwe kan si ekeji ati beebee lo. Awon miran mu ayo ati idunnu wa; omiran nmu itiju ati abamo wa tobe ti mo ti nwo ejika mi bi boya enikan wa nibe to nri awon akosile naa. Faili(dossier) to ni akole “Awon Ore” lo tele ti akole “Awon Ore Ti Mo Ti Da”.
Awon akole wonyi bere lati awon iwa irira wobia aye yi titi de awon ise buburu miran ti a ko lee daruko. “Awon iwe ti mo ti ka ri”, “Awon oro ti mo ti pa”, “Awon itelorun ti mo ti fi te ara mi Olorun”, “Awon awada ti mo fi rerun seyin”. L’otito awon miran pa ni lerin gidi. “Awon igbe ti ke mo awon arakunrin mi”. Omiran ti ko se e fi rerin: awon kikun ti mo ti kun mo awon obi mi”, awon ohun ti mbe ninu iwe wonyi ko dekun ati maa jo mi l’oju. Opo igba ni awon iwe pelebe wonyi npo ju ohun ti mo lero lo. Igba miran won a si kere ju ero mi lo pelu.
Igbe aye ti mo ti gbe seyin yii bori okan mi mole pupo. O wa lee seese fun mi lati fi ogun odun ko egbeegberun ona egberun awon akosile wonyi, sinu iwe pelebe wonyi? Sugbon iwe kookan yi fi idi otito mule. Ati pelu pe owo ara mi ni ko fi ko won. Ti mo si fowo siwe naa nikookan.
Nigbati mo fa iwe to ni akole “Awon Orin ti mo ti fetisi/gbo ri”, mo lee ri daju pe aye ti iwe pelebe (card/carte) yii gba kun fofo ni, a fun won jo po ni iwon opa meji si meta, sibe n ko ti iri opin
Irufe orin ti won je, sugbon won po gege bi iwon akoko ti won ti wa. Nigbati mo de ibi faili/dossier “Awon ero ifekufe”, otutu kan gba gbogbo ara mi koja, nko fe lati sii pupo lati ma lee mo bi o ti po to, mo fa okan jade ninu a won iwe naa lati wo ohun ti a ko sibe. Aare mu mi lati ri pe a ko iru nkan bee sile ni awon akoko naa.
Lojiji inu mi ru fun ibinu. Ero kan to mi wa pe “won ko gbodo ri iru awon iwe yi, mo ni lati baaje ni”. Iye won ko jamo nkankan fun mi mo, mo gbodo jo won ni. Sugbon bi mo ngbiyanju lati tu a won iwe naa sile yara naa, ko seese bi no jan an mole to won ko jade, mo okan jade ninu iwe naa lati faa ya, bi irin ni o ri, ti ko see run tabi faya bi o ti fele too ni. Ara mi ko lele mo.
Ni ijakule on ailee ran ara eni lowo, mo da faili/dossier naa pada si ipo re. Mo fi ori ti ogiri, ironu mi fo lo, mo si nkaanu ara mi. Leyin eyi, mo ri akole “awon ti mo ba waasu iyinrere fun”, owo faili/dossier yii dan ju awon to ku lo, bi enipe a tile loo ri rara. Mo fa owo re, apoti kekere bi iwon atelewo lo jade simi lowo, gbogbo iwe inu re ni mo lee ka lori ika owo mi.
Nigbanaa ni omije njade l’oju mi. Ekun de, mo si bere si sokun. Mo sokun titi gbogbo inu mi bere si dun mi, ara mi si ngbon. Mo wole lori eekun mi, mo si nsokun. Mo sokun lati inu itiju, oju ti mi gidigidi fun awon ohun gbogbo wonni ti mo ri pe mo se. Lati inu omije mi, mo nwo awon faili/dossier bi o ti po to, ko gbodo si enikeni to gbodo ri yara yii, enikeni. Mo ni lati fi kokoro tii pa, ki nsi fi kokoro naa pamo.
Sugbon, igba naa, mo gbiyanju lati da omije naa duro. Mo si ri I. Rara, jowo ki ise Oun. Beeko, ki ise ni ibi yii. Ah! Ki ise elomiran, bikose Jesu.
Ni ailee ran ara mi lowo, mo nwo bi o ti nye inu awon failing/dossier ati iwe inu won ni ikookan ti o si nkaa. Nko lee farada isesi Re si won. Mo gbiyanju lati wo oju Re, mo ri ikaanu ti o ju temi lo l’oju Re. Ni alaibikita, O lo sibi failing/dossier to buruju, kini idi re to fi ni lati ka oro inu re nikookan? Nigbose O yi oju Re sodo mi iha keji yara naa, O wo mi pelu aanu ni oju Re, sugbon iru ikaanu yii ko ni ibinu/irunu ninu rara. No teriba, mo fi owo bo oju, mo tun bere ekun sisun. O rin wa sodo mi, O fi owo Re si ejika mi. Iba ti so oro pupo. Sugbon ko so gbolohun kan ju pe, O fi owo Re si ejika mi, O si mba mi sokun. O dide kuro lodo mi pada si bi faili/dossier ara ogiri naa. Bere lati igun yara kan, O mu faili/dossier kan, O mu iwe inu re nikookan, O si nko oruko ara re sori oruko mi ati ibi ti mo fowo si nisale iwe naa.
“ Rara”, mo kigbe, mo sare sodo Re. Gbogbo ohun ti mo le ri so ni “Rara, beeko, bi mo ti nfa iwe naa moo lowo. Oruko Re ko gbodo si ninu iru iwe bi eleyi. Sugbon nibe ni a koo si, o pon, o ki, o si wa laaye. Oruko Jesu go temi mole, eje Onu tikarare li o fi koo.
O fi suuru da iwe naa pada saye re. O rin erin, O si tun tesiwaju lati maa ko oruko Re sori temi. Nko to pe mo moye bi o ti tete yara, sugbon ni iseju pe, o dabi mo gbo bi O ti npa faili/dossier to keyin de. O si pada to mi wa. O fi owo re le ejika mi, O wipe “O pari”. I dide duro, O si mu kuro ninu yara naa. Ko si kokoro nibi ilekun naa, nitori awon iwe akosile si tun ku lati tun maa ko sii.
* * * * *
Bawo ni iwe akosile re t'oni se ri o, bi a je olotito si ara wa, pelu abamo ati irobinuje okan gba ikuna wa ninu ero okan ati ise. Awa pelu, ero ti a fi pamo ati ese ikoko to a se pamo ni lati mu itiju ba wa. Bibeli so ninu iwe Roomu 2:16 wipe “Olorun yio ti ipa Jesu Kristi se idajo asiri eniyan gege bi iyinrere mi”. Aposteli Peteru waasu wipe, “Nitorina e ronupiwada, ki e tun yipada, ki a le pa ese yin re, ki akoko itura ba ti iwaju Oluwa wa”. Jesu a ti nu ese re nu bi tabi won si nle o kiri loni?
Iwo a fe d'ominira loni bi? Nje ise ati ero ateyinwa a n rin okan re mole bi? Eru wuwo nla ni ese maa
lori okan ati igbesi aye wa. “Bi awa ba wipe awa ko li ese, awa tan ara wa je, otito ko si si ninu wa”. (1 Johanu 1:8), “Nitori iku li ere ese; sugbon ebun ofe Olorun ni iye ti ko nipekun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa “, (Roomu 6:23).
Jesu nfun ni ni idariji. O wa si aye lati ta eje Re sile fun awon elese. Eto igbala wa di pipe wayi. Nje o fe do mimo bi? “Nitorinaa bi omo ba so yin di omnira, e o di omnira nitooto”,(Johanu 8:36), (O.Dafidi 51). Wa sodo Jesu nisisiyi! Ronupiwada ki o so jewo awon ese re. “Bi awa ba jewo ese wa, olooto ati olododo li on lati dari ese wa ji wa, ati lati we wa nu kuro ninu aisododo gbogbo”.(1 Johanu 1:9). Gbekele Jesu lati se amona igbe aye itelorun/ifokanbale pelu Re. Yio pese itosona fun igbesi aye re.
IYARA NAA
Copyright 1995-New Attitude/Joshua Harris.