Kíni Ìbẹ̀rù?
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run
Ìbẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la
Ìbẹ̀rù Ìjákulẹ̀/Ìkùnà
Ìbẹ̀rù Ìjìyà
Ìbẹ̀rù Ikú.
DI ÒMÌNIRA LỌ́WỌ́ ÌBẸ̀RÙ
Ìbẹ̀rù, ọ̀tá ńlá kan ni tí ímáa kọjú ìjà sí ìran ènìyàn láì ka ọjọ́-orí tàbí ẹ̀yà ati ni ilẹ̀ ayé yíká-yíká. Ó ní àrékérekè, o ńpa ń kàn rún, májèlé ni fún àwọn èrò ọkàn, a si máa jí àlàáfíà inú ọkàn ẹni lọ , a mú ilé aye sú ni. Ó ńfa àìbalẹ̀ ọkàn, àìsimi, ìjayà, ìrunú , ati ojo ; ah, irú ipò ti kò fún ni láyọ̀, ti ẹnìkẹ́ni kò ni ìfẹ́ sì bi èyí! A máa ńbẹ̀rù rògbòdìyàn ati ìyípadà, ìkùnà ati ìjákulẹ̀. Àwọn míràn a máa bẹ̀rù àìsàn àti ìyà. Àwọn a si máa bẹ̀rù pé ibi leè ṣẹlẹ̀ si àwọn ẹnití àwọn fẹ́ràn. Àwọn míràn ńbẹ̀rù ẹlòmíràn tàbí èrò ọkàn wọn. Àwọn míràn a máa bẹ̀rù òkùnkùn, tàbí dídáwà ni àwọn nìkan. Ọ̀pọ̀ ńbẹ̀rù láti kú tàbí àwọn ohun ti kò mọ̀. Àwọn onígboyà kan wa to mbẹ̀rù àìdánilójú ìgbàlà ọkàn rẹ̀. Tàbí pé bóyá Ọlọ́run kò tíì dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji òun. Wọn kò bẹ̀ru láti kú nìkan, ìwà láàyè tún je ìbẹ̀rù fun wọn pẹ̀lú. Jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ìbẹ̀rù máa ǹyọ́ wọ ọkàn ẹni láìpariwo, a ṣòro láti mọ̀ pé a ti wà lábẹ́ iṣẹ́ ìparun rẹ̀ ti o burú. Àní ẹ̀rù kínún/tíntín, dàbí aró òǹkọ̀wé kínún/tíntín nínú Ife omi kan, a si sọ gbogbo omi di aláwọ̀ míràn. Níwọ̀n ti a kò bá di isàn omi tóóró, a di èyí tí o sàn kan àwọn èrò ọkàn míràn nínú ẹni, ti à sí mú rúdurùdu ba ọkàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti ronú, “Ohunkóhun ti íse òótọ́ …. ọ̀wọ̀ …. títọ́ … mímọ́ …. fífẹ́ …. ti o ni ìròyìn rere”.(Filip.4:8).
Ìgbésí ayé ni ẹ̀ka púpọ̀, ogun ni ilé ayé, ṣùgbọ́n wàhálà ti òde kò gbọdọ̀ ba àlàáfíà ti inú ọkàn jẹ́. Ìbẹ̀rù ti inú ni a ni láti àbójútó. Ìbẹ̀rù a wọlé de níwọ̀n ti kò si ọ̀nà àbáyọ fún ìnilò to se kókó. Ọkàn wa, ti a da ni àwòrán Ọlọ́run a bẹ̀rẹ̀ si kígbe pe. Nígbà tí a ba jìnnà si Ọlọ́run, dandan ni ki ọkàn kun fun onírúurú àṣìṣe gbogbo, kò dàbí eni pé ohun gbogbo dojúrú pọ̀ mọ́ ara wọn àti Ìbẹ̀rù lórísìrísìí.
Kíni Ìbẹ̀rù?
Ìbẹ̀rù je ìhágàgà ti o jáde láti inú ìmòye pe inú Ọlọ́run kò dùn si ìgbé ayé ẹni. Ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ni ọjọ́ ti Ádámù ati Éfà gba abá ti Sátánì fún wọn lòdì si àṣẹ Ọlọ́run pa fún wọn “ẹ̀yin kò gbọdọ̀ je nínú èso igi ti ḿbẹ láàrin ọgbà”. Nítorí àìgbọràn, wọ́n d’ẹ̀sẹ̀, wọ́n si fi ara wọn pamọ́ kúrò lójú Ọlọ́run. Ọlọ́run pè wọ́n, Ádámù dáhùn wípé, ”Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú ọgbà, ẹ̀rù si bà mí ”(Gẹ́nẹ́sísì 3:10).
Sátánì a máa ṣiṣẹ́ nínú òkùnkùn. Kò si lee ṣiṣẹ́ nínú ìmọ́lẹ̀ nítorí, “ ìmọ́lẹ̀ li Ọlọ́run, òkùnkùn kò si sí lọ́dọ̀ rẹ rara”(1 Jòhánù 1:5).. Sátánì mọ àìlera wa, wọn si jẹ́ àwọn on a ti o máa ń gbà mu onírúurú èrò ọkàn wa ati Ìbẹ̀rù. Á wa ọ̀nà̀ láti pa òtítọ run, ki o si fi èké da wa lọ́kàn rú. Ti a ba pa nkàn wọ̀nyí mọ nínú òkùnkùn ọkàn wa, Sátánì yoo tẹ̀síwájú iṣẹ búburú rẹ láti mu ìrẹ̀wẹ̀sì ati ẹ̀rù ba ọkàn. A le ṣẹ́gun rẹ, ki a si lée sẹ́yìn ti a ba ti àṣírí rẹ̀ sínú ìmọ́lẹ̀.
Sátánì máa ńlo àǹfààní ìbẹ̀rù ayé wa. Ó tilẹ̀ máa ǹmú ki àwọn àǹfààní ibi re yii le koko, dàbí ẹni pé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀ràn náà ri, pẹ̀lú ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí míràn. Àwọn ọ̀nà wa a si máa dúdú síi, ẹrú wúwo àyà wa a si tún máa wúwo síi títí, a o fi so ìrètí ìdáǹdè nu. Rántí, Ọlọ́run tóbi jù gbogbo ìbẹ̀rù lo. Ọpẹ́ ni fun Ọlọ́run pe nínú Ìfẹ́ Rẹ̀ ti o ga, o ti ṣ’ètò láti gba wa lọ́wọ́ ìdájọ́ ikú ayérayé nínú ọ̀run àpáàdì. O ran Jésù, Ọmọ Rẹ̀ kan soso si ayé láti jẹ olùgbàlà wa. Nínú ikú ìrúbọ rẹ lórí igi àgbélébùú ti Kálífáárì, O tẹ́ ìdájọ Ọlọ́run lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ́rùn. Nínú ìràpadà yìí, Ọlọ́run ti pèse ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti gbà wa lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, nítorí ìbẹ̀rù je àbáyọrí ẹ̀ṣẹ̀, Jésù si ti ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ ati àwọn ipá rẹ gbogbo.
Ìtàn ọ̀dọ́mọkùnrin kan to máa mbẹ̀rù láti rìn nínú òkùnkùn li òun nìkan, ṣùgbọ́n nígbà tí bàbá rẹ̀ ba ḿbaá lọ ti o si di ọ̀wọ́ rẹ mú, ìbẹ̀rù a si fò lọ. Òkùnkùn kò ni ẹ̀rù kankan mọ, nítorí ìfẹ́ ati ìgbẹ́kẹ̀lé ti o ni si bàbá rẹ̀, ti o si mọ dájú pe yíò tọ́jú òun. Ibí yìí ni kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́gun máa wa fún wa láti di òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀rù. A gbọ́dọ̀ kọ́ láti mọ Bàbá wa ti ḿbẹ li ọ̀run mọ̀ dáradára. Ní ṣíṣe ìdàmọ̀ rẹ yìí, ti a si jọ̀wọ́ gbogbo ìgbésí ayé wa leè lọ́wọ́ pátápátá, ti a si fi ọwọ́ wa lee lọ́wọ́ ni ààbọ̀, a o sọ ohun gbogbo to ǹyọ ọkàn wa lẹ̀nu fún, àti gbogbo ìṣoro ti ńfa èèyàn sínú ìrònú on ìkáríbọtan. Ki a si fi tọkàntọkàn se àwárí ojú rẹ, ní yíyọ̀ǹda ara ẹni pátápátá fún Ọlọ́run ati ìfẹ́ rẹ̀, ka si máa bàa lọ li jíjẹ́ olótìítọ ati olùgbọ́ran. “Ìbẹ̀rù kò si nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti o pe ńlé ìbẹ̀rù jáde: nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹnití o bẹ̀ru kò pe nínú ìfẹ́.”(1 Jòhánù 4:18).
WhatÌbẹ̀rù Ọlọ́run
Ìbẹ̀rù ìdájọ Ọlọ́run yii, ti o ba lee mu èèyàn wa si ìronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, o lee di agbára pàtàkì nínú ìgbésí ayé ẹni. “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:”,(O. Dáfídì 111:10). Eyii je ìtọ́kasí ti o ni ọ̀wọ̀ nínú, a ni ìmọ̀lára re, o si dára. A ńrí títóbi, òdodo , ìdájọ, Ifè, àánú, ọgbọ́n, ati wíwà láàyè láéláé/àìkú tí Ọlọ́run yìí ni apákan. Òun ni Olùmọ̀-ohun gbogbo, ẹnití o ni gbogbo agbára, ẹnití o wa níbi gbogbo. A si mọ èyí pé, wíwà wa pàápàá láti ọwọ́ rẹ, a si wa níwájú re gẹ́gẹ́ bi ẹ̀dá ọwọ́ rẹ. Ẹ̀rù a máa ba wa láti ba irú Ọlọ́run báyìí nínú jẹ́. A mọ pe òdodo Ọlọ́run da àwọn to ǹgbé nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́bi iná ọ̀run àpáàdì. “Nítorí bi àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí àwa ba ti gba ìmọ̀ òtító, kò tún si ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ, bíkòse ìrètí ìdájọ ti o ba ni lẹ́rù, ati ti ìbínú ti o múná, ti yíò pa àwọn ọ̀tá run”.(Hébérù 10:26-27). Ìmòye yii ǹmú ìbẹ̀rù wa fun ẹ̀ṣẹ̀. Bi a ti se da Ọlọ́run mọ gẹ̀gẹ̀ bi ọ̀rẹ́ ti ara wa nipa ìronúpìwàdà, ìdáríjì, ati ìgbọ́ran, iṣẹ́ ìsìn yíò di èyí ti ǹti ọwọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run se amọ̀nà, nipa ìfẹ́ ati ìdúpẹ́ fun ẹ̀bùn ìgbàlà ti kò see f’ẹnu sọ. Ìbẹ̀rù wa si Ọlọ́run, ki íse irú èyí ti mu ìpayà ba ọkàn, ṣùgbọ́n èyí ti ǹmú ìfẹ́ wa jinlẹ̀ fun Ọlọ́run si ni. Nígbà tí a ba loo ni ki kún ọkàn wa, irú ìbẹ̀rù yí yíò mu wa máa ṣẹ́gun àwọn ẹ̀rù míràn. Kíni ìdí rẹ ti àwọn èèyàn fi ńgba òjìji ìbẹ̀rù láàyè nínú ọkàn wọn, ìrònú wọn a si dààmú, ti yíò si mu òkùnkùn sú ni ọ̀nà ìgbésí ayé wọn? Ọ̀nà Ọlọ́run ni ọ̀nà àlàáfíà ati ìgbẹ́kẹ̀lé.
Àpẹẹrẹ Àpọ́sítélì Pétérù, nígbà tí Jésù sọ fún un láti máa rìn lórí rírú omi òkun Gálílì. Ẹ̀rù kò ba Pétérù rárá bi o ti ń rìn lọ àfi ìgbà tí o gbé ojú rẹ kúrò lára Olúwa, to si ǹwo rírú omi to ḿba ni lẹ́rù. Nígbà náà ni o bẹ̀rẹ̀ si írì.(Mat. 14:24-31). Bi a ti ńwá òmìnira kúrò lábẹ ìbẹ̀rù, ti a si ńfi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Ọlọ́run, Emi mímọ re yíò máa ba wa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kékeré. Bi a ba si ti wo ojú rẹ ju wíwo ìbẹ̀rù wa, rírú omi yíò dúró jẹ́ẹ́ li àyíká wa. Yoo fi ìdáhùn fun àwọn ìbéèrè ọjọ́ wa gbogbo, yíò fi ìdánilójú rọ́pò iyèméjì, ti yíò si di ọwọ́ mu pẹ̀lú ìtura. Pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ re, a lee ṣẹ́gun ipá ati gbogbo iṣẹ búburú ti o ti se.
IÌbẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la
Àwọn ìjìnlẹ̀ àìmọ̀ bi ọjọ́ ọ̀la yíò ti ri máa mu àwọn èèyàn wa nínú àìsimi ọkàn, ni òròwúrọ̀, wọn a ji sínú àìmọ̀ bi o ti lee jẹ́. Wọ́n dojú kọ ìpayà pe “tó bá, tó bá ńkọ́?” bi ọkàn won ti ńlá onírúurú ìrònú ti da ọkàn láàmú lo “Ẹ máse àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nipa àdúrà ati ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, e ma fi ìbéèrè yin hàn fun Ọlọ́run” (Fílípì 4:6). Nípa ìyọ̀nda ọjọ́ ọ̀la le Ọlọ́run lọ́wọ́, a o lee jọ̀wọ ẹ̀rù àwọn ohun ti a kò mọ wọ̀nnì lee lọ́wọ́. Dánwò, ki o si ríi.
Ọ̀pọ̀ lo mbẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la nítorí ti wọn kò ni ìdarí/ètò fun ìgbésí aye won. Ni àìmọ ibi tí àwọn ńrè, ẹ̀rù èyí náà pàápàá a máa mu ọkàn wọn sàárẹ̀. Ọlọ́run mọ ohun to wa níwájú, ti won ba le gba láàyè láti tọ wọn, won ki yíò wa nínú ìgbésí aye ta ńgba kiri, ṣùgbọ́n èyí ti o ńlọ tààrà si ilé.
Ọlọ́run ti se ìlérí láti je olótìítọ si àwọn ti wọn gbẹ́kẹ̀ wọn lee, bi àìlóye ojo ọ̀la tilẹ̀ yí wọn ká. Ǹjẹ Ìwọ gba èyí gbọ́ bi? Bi o ti wù ki ìjì náà le to, tàbí dúdú òkùnkùn òru náà, tàbí gíga òkè náà, Òun yíò mu o làájá.
sÌbẹ̀rù Ìjákulẹ/Ìkùnà
Ifè ọkàn ẹni ni láti se àṣeyọrí , ṣùgbọ́n a máa mbẹ̀rù pe a ǹdá ara wa, ẹbí wa ati ìgbésí ayé wa kulẹ̀. Àṣìṣe nínú ohun ti a yàn, tàbí tí ìlànà to lòdì máa ḿba wa lẹ́rù.
Ọlọ́run pàṣẹ fun Joshua, “Se giri ki o si mu àyà le; máse bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àyà ki o máse fò ọ; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ wa pẹ̀lú rẹ níbikíbi ti ìwọ ba ǹlọ”(Joshua 1:9). Nígbà tí a ba fi ìgbésí ayé wa sábẹ́ ìtọ́ni Olúwa, ìkùnà àtẹ̀yìnwá wa kò ni je òpin; wọn lee di àtẹ̀gùn fun àṣeyọrí tuntun.
Ìbẹ̀rù Ìjìyà
Ará wa máa wárìrì láti ronú nipa ìrora ẹran ara wa, ìsọ̀rọ̀ òdì to ńdun ni, ìpayà dídáwà ni ẹnìkan ati ìbànújẹ́. Ọlọ́run ki I panimọ́ kúrò nínú gbogbo Ìjìyà ṣùgbọ́n O máa ńfún ni ní oore-ọ̀fẹ láti làá kọjá. O sì tún se ìlérí àlàáfíà ìdánilójú ni àárín wàhálà. “Ọlọ́run li ààbò wa àti agbára, lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ni ìgbà ìpọ̀njú. Nítorí náà li àwa ki yíò bẹ̀rù, bi a tilẹ̀ si ayé ni ìdí, ti a si sí àwọn òkè ńlá nípò lọ si inú òkun:”(Ó. Dáfídì 46:1,2). Bi a ba ni ìfẹ́ Ọlọ́run, a si máa ńlo Ìjìyà fun ire wa. Ìjìyà ńpèsè àǹfààní láti mọ Ọlọ́run ati láti dii agbára Rẹ mú. O ǹmú èèyàn jinlẹ síi nínú ìwà pẹ̀lú ìmòye ọkàn. Ìjìyà a máa sọ èèyàn akin tàbí òmìrán, èwo ni ìwọ́ ńfẹ́?
Ìbẹ̀rù Ikú
Àwọn èèyàn a máa bẹ̀rù ikú, ìdágbére jẹ́ ìrora to ga láti se. A ni láti di ìbéèrè láéláé ni mú ti o sọ pe “Bi èèyàn ba kú, yíò si tún yè bi?”(Jóòbù 14:14). Jésù wa da wa nídè lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù ikú (Hébérù 2:14,15). Idi èyí ni o se kú ti o si tún jíǹde, ti o si se ìlérí pe “Nígbà die síi, aye ki yíò si rí mi mọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin o ri mi: nítorí tí èmi wa láàyè, ẹ̀yin o wa láàyè pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:19). Pẹ̀lú Rẹ, ikú ki íse ọ̀nà si ofo/asán , ṣùgbọ́n ẹnu ọ̀nà ńlá dídán ti o ńtàn si ìgbésí ayé tuntun. “E máse jẹ́ ki ọkàn yin dàrú: … Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé li o wa: ìbámáse bẹ́ẹ̀, èmi ìbá ti so fun yin. Nítorí èmi ńlọ í pèsè aye sílẹ fun yin.”(Johannu 14:1,2). Yíò je ayé ti a ti pèsè sílẹ tan fun àwọn ti o ti pèsè ara wọn sílẹ̀.
Se o ti múra tan, o a ti ronúpìwàdà kúrò nínú ìgbé ayé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ? Ìronúpìwàdà ǹmú ìkáànú ọkàn wa lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ati ìyípadà kúrò nínú ìgbé ayé ògbólógbòó ni. Ìgbà wo ni o tọ Jésù wa nínú àdúrà ti o si sọ gbogbo ẹ̀rù àníyàn, ìdààmú ati ìbẹ̀rù re fun. Jésù wipe “E wa sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin ti ńsiṣẹ́, ti a si di ẹrù wúwo le lórí, èmi o si fi ìsinmi fun yin.”(Mat. 11:28). Irú ìpè bi èyí! Irú ìlérí bi èyí!
Wa pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé, àdúrà ati ìrètí, Iwo yíò si ni àlàáfíà ọkàn.
Wa ki o si ni àwọn ayọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ti o kun fun igbe aye ìsinmi. Ọlọ́run ńpè ọ láti gbẹ́kẹ rẹ le Jésù ki o si d’òmìnira, di òmìnira lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. Wa!
Jesu