John N. Reynolds
Ọkàn nínú àwọn ẹjọ́́ ti o gbádùn jùlọ ni tíì isọji ti mo rántí ni ti Ọ̀gbẹ́ni George Lennox, olókìkí olè ti n máa jí ẹṣin gbé ni agbègbè ìlú Jefferson. Ọ̀gbẹ́ni yìí nlo ìgbà kejì rẹ̀ ni ile ẹ̀wọ̀n ni àkókò ti ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Ìjọba ìbílẹ̀ ti Sedgwick ni o ti kọ́kọ́ júù sí ẹ̀wọ̀n ìgbà kíní nítorí ẹ̀sùn kan náà pé o ji ẹṣin gbé.
Ni àkókò òtútù ni, ní ọdún 1887 àti 1888, nígbà tí Lennox ń ṣiṣẹ́ níbití a ti nwa èédú. Ibití o ti ńwa èédú náà dàbí ẹni pé o l’éwu fún u, o lọ sọ fún alábòójútó iṣẹ́ náà. Ọ̀ga na se ìwádìí, nigbati o sì ríi pe ibẹ̀ kò l’éwu, o pàṣẹ pe ki o pada lọ ṣe iṣẹ́ ẹ rẹ̀. Ọkùnrin arúfın yií ṣe ìgbọràn, o si pada lọ si ibi iṣẹ́ rẹ, ko si ti ju nkan bi wakati kan lọ lẹhin ti o ti pada, nigbati orule ibiti o ti nse ise na ya bò ó mọ́lẹ̀ bámúbámú. O si wa ni ipo yi fun odindi wákàtí méjì.
Nígbà tí wọ́n ko ri ọkùnrin yi ni ibi onje àsáálẹ́, nwọ́n ran enia lọ lati lọ wa a kiri. Nwọ́n si ri i lábẹ́ pàǹtírí ti o ya bo o mọ́lẹ̀. O si dabi ẹni pé o ti ku. Nwọ́n gbe e sókè, nígbàtí oníṣègùn ti o wa ni ile ẹ̀wọ̀n sì ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní tán, o sọ fun wọn pe o ti ku. Nwọ́n si gbe òkú rẹ lọ si ile-ogun nibiti nwqn. ti we e, nwọn wọ̀ ọ́ ni aṣọ òkú fún ìpalẹ̀mọ́ láti sin i. Nwọ́n se posi rẹ, nwọ́n si gbe pósí náà wa si ilé-oògùn. Oniwasu ti yíò ṣe isin ìdágbére asekẹ́hin fún un ki a to sin i ti de si ilé-oògùn na pẹ̀lú. Àwọn òṣìṣẹ́ ilé-oògùn si pàṣẹ fun àwọn ẹlẹ́wọ̀n lati gbe òkú rẹ̀ lati yara kini lọ sínú pósí ti o wa ninu yara keji. Nwọn si ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn gbe òkú náà ni ori, ekeji si gbe e ni ẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n bi nwọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ de ìdajì ile na, eyiti o gbé òkú náà lori fi ẹṣẹ̀ kọ, o si ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n, ori òkú sí bọ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀. Bí orí òkú náà tí bọ́ lulẹ̀, ìyàlẹ́nu ńlá ni o si jẹ́ fún àwọn ti o wà níbẹ̀ lati gbọ́ bí òkú náà ti ń mi ìmí ẹ̀dun. Láìpẹ́ òkú náà la ojú rẹ̀, gbogbo àwọn àmì alààyè si hàn lára rẹ̀ pe kò tíì kú. Lẹ́ẹ̀kanna nwọ́n ránsẹ́ si oníṣègùn, ṣùgbọ́n o to nkàn bíi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ki o tọ́ dé. Ki o si to dé, ẹnití o ti kú yi bèrè fún omi, èyí tí ó fẹ́ máa mu nígbàtí oníṣègùn náà de.
Lẹ́sẹ̀kanna, nwọ́n gbé pósí kúrò nwọ́n sì tún fi sin òkú ẹlẹ́wọ̀n míràn lẹ́hìn ìgbà náà. A mú aṣọ ìsìnkú ti o wà lára rẹ̀ kúrò, a si mú aṣọ ẹlẹ́wọ̀n fún un dípò rẹ̀. Nígbàtí oníṣègùn si tún àyẹ̀wò ara rẹ̀, ó ri pé egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ṣẹ́ l’ọ́nà méjì, àti pé, ó si ni ọgbẹ́ pẹ̀lú. Lẹ́hìn tí o ti dúró ni ilé-oògùn fún oṣù mẹ́fà, o tún padà lọ si ibi iṣé rẹ̀.
Láìpẹ́ lẹ́hin ikú rẹ̀ ni mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ìrírí wọ̀nyí tí ó yàtọ̀ láti ẹnu ọ̀kan nínú àwọn alábàáṣisẹ́pọ̀ ọkùnrin náà. Níwọ̀n ìgbátí o ti jẹ́ àníyàn mi láti mọ ohun ti o ṣẹlẹ̀ sí Lennox lẹhin náà, mo bẹ̀rẹ̀ si wa ọ̀nà ti ngọ́ fi lè bá ọ̀gbẹ́ni Lennox yìí pàdé ki nle bá a sọ̀rọ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ng ó fi lé e gba ìtàn ara rẹ̀ lẹ́nu òuntìkálárarẹ̀. Ṣùgbọ́n àyè lati ṣe èyí ko tètè ṣí sílẹ̀ fun mi bí kò ṣe lẹ́hìn oṣù díẹ̀. Níkẹyìn èyí, àyè náà ṣí sílẹ̀. A gbé mi kúrò ni ibi tí mo ti ń wa èédú lọ si inú túbú kan láti gba ìròhìn ọdọọdún iṣẹ́ ibẹ̀. Ni ọjọ́ kan, nígbàtí a ń sọ̀rọ̀ nípa bí ọkùnrin yìí ti kú lẹ̀ẹkán rí ti o si tún yè, ni o ń kọjá lọ ni àkókò náà gan. Àwọn ti o wa lọ́dọ̀ mi si tọ́ka si i fún mi. Ko pẹ́ lẹ́hìn ìgbà náà mo kọ̀'wé kékeré kan si i pé ki o wa sí ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́, o si se bẹ́ẹ̀, mo si wa mọ̀ọ́ dáadáa. Láti ẹnu òuntìkára rẹ̀ ni mo si ti gba ìtàn ìyàlẹ́nu yi.
George Lennox jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ti ko le ju ọgbọ́n ọdún lọ. Ògbójú olè àti arúfin ọIọ́kàn líle sì ni. Ọ̀mọ̀'wé gan si ni ọ̀kunrin na, bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ fi i hàn gẹ́gẹ́bí amòye ati ẹnití o jáfáfá.
Ohun ti o jẹ́ ìyàlẹ́nu jùlọ nínú ìtàn rẹ̀ nì àwọn nkàn ti on pàápàá sọ nipa àkókò ti o kú yìí. Àwọn ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí o ti nsọ wọ́n fún mi.
O wípé, "Mo ti ni ẹ̀rí ọkan pé ohun búburú kan yíò ṣẹlẹ̀ sí mì láàrọ̀ ọjọ́ náà. Nípa èrò ohun búburú yìí tí ko si jẹ́ ki ara mi balẹ̀ rárá ni mo fi lọ sọ́dọ̀ Mr. Grason, ọ̀gá ibi iṣẹ́ wa pé kí o wa wo ibi tí mo ti ńṣe iṣẹ́ nitoripe emi ko ni ìfọ̀kànbalẹ̀ níbẹ̀. Ọ̀gá náà si wa wo ibẹ̀. Lẹ́hìn tí o ti wò ó tán, ó pàṣẹ fún mi láti padà lọ ṣe iṣẹ́ mi nitoripe on kò ròpé ewú wa níbẹ̀ rárá àti wipe mo ń yọ àyọ̀jù.
Èmi náà si padà si ibi iṣẹ́ mi. Kò ju wákàtí kan lẹ́hìn ti mo ti ńwalẹ̀ nígbàtí ilẹ̀ si ṣú lójijì. Ó si dàbí ẹni pé ilẹ̀kùn irin ńláńlá kan ṣí sílẹ̀, mo si gba ti àárín rẹ̀ kọjá. Nígbà náà ni èrò kan wa s'inu ọkàn mi pe mo ti kú, ati pe mo ti wa ninu aiye míràn. Èmi kò tún le è ri ẹnikẹ́ni mọ́, tàbí ki ngbọ́ ohunkóhun. Mo bẹ̀rẹ̀ si rin lọ kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀kùn irin ńláńlá yi lai mọ ohun ti o mu ki ńṣe bẹ́ẹ̀. Nígbàtí mo si ti rìn jìnnà díẹ̀, mo de etí odò ńlá kan. Ilẹ̀ ko su bẹ́ẹ̀ni ko mọ́ to bẹ́ẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ tí ó wa kò ju èyí tí o ma ń wá níwájú ìràwọ̀ ba wa ní àwọsánmà ti ko si òṣùpá. Èmi kò ti dúró pẹ́ ni etí odo yìí nígbàtí mo ń gbọ́ iro ohùn kan lati inú omi wa, kò si pẹ́ lẹhin èyí nígbàtí ọkùnrin kan ti o wa nínú ọkọ̀ ojú omi jáde si'ta, ti o si ńwa ọkọ̀ rẹ̀ bọ̀ níbití mo dúró sí.
Èmi kò leè sọ̀rọ̀ mọ́. O wo mi fun ìṣẹ́jú kan, ó si sọ fún mi pe emi ni on tọ̀ wa láti gbé mi kọjá ninu ọkọ̀ òun si òdì kejì odò náà. Mo se igbọ̀ran lai sọ ohun kan. Mo ti fẹ́ bèrè ir Ni ú ẹnití o jẹ́ àti ibi tí mo wà. Ṣùgbọ́n o dabi ẹni pé ahọ́n mi ti lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi, emi ko si leè sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan. Níkẹyìn a de òdì kejì odo, mo jade kúrò nínú ọkọ̀ oju omi náà. Atukọ̀ náà si nù mọ́ mi lójú.
Báyìí ni o ku emi nikan, nkò sì mọ ohun tí èmi yóò ṣe. Ṣùgbọ́n, nígbàtí mo wo iwájú mi, mo rí ọ̀nà meji ti o kọjá láàrin àfonífojì ti o sókùnkùn biribiri. Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀nà meji wọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà ti o gbòòrò ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ma ń rìn, èkejì si jẹ́ ọ̀nà tóóró ti o gba ti ibòmíràn lọ. Laisi iyèméjì, mo gba ti ọ̀nà ti o gbòòrò yíì . Èmi ko ti rìn jìnnà tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí o dàbí ẹni pé ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si ṣú. Láti ìgbà dé ìgbà, ìmọ́lẹ́ si máà ń tàn láti òkèèrè wá. Ìmọ́lẹ̀ yíì sì ni mo fi rin ìrìn-àjò mi na."
Láìpẹ́ mo pàdé abàmì ẹ̀dá kan tí o ṣòro fún mi láti se àpèjúwe rẹ. Ohun ti mo lè ṣe kó ju pé kí ń sáà se àpèjúwe díẹ̀ nípa ìrísí rẹ̀ ti o bani lẹ́rù. (Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o jọ ènìyàn, síbẹ̀ síbẹ̀ o tóbi ju ẹnikẹ́ni tí mo ti bá pàdé ri lọ. Ó gùn tó ẹṣẹ̀ ẹ bàtà mẹ́wàá. O si ìyẹ́ ńláńlá ni ẹ̀yìn rẹ̀. Ó dúdú tó èédú ti mo ti ń wá jáde ninu ilẹ̀. Ó si wà ni ìhòòhò pátápátá. Ó gbé ọ̀kọ̀ kan ti o gùn to ẹṣẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀dogun lọ̀wọ̀. Ojú rẹ̀ tí ó tóbí ó sì ńjó bi ẹyin inà. Àwọn ẹhín rẹ̀ funfun bi òkúta iyebíye, ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu nwọn si gùn to ìdáméjìlá ìwọ̀n ẹṣẹ̀ bàtà kan. Bí a ba tilè pé imú tirẹ̀ ni imú rárá, o tóbi púpọ̀, o si fẹ̀. Irun Orí rẹ̀ gun, o wúwo, ó sì ṣe ṣákișàki, o si kan èjìká ńlá rẹ lẹ́hin. Ohùn rẹ̀ si dabi igbe kìnnìún.
"Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ kan ti kọ́kọ́ tàn ni mo ri ọkùnrin náà. Mo si bẹ̀rẹ̀ si ńgbọ̀n. Ó gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè bi ẹnì pé yíò fi gún mi. Mo dúró lẹ́sẹ̀ kanna. Mo si gbọ́ ti o sọ fun mi pẹ̀lú ohùn rẹ̀ ti o bani lẹ́rù pe kí ń tẹ̀lé on; pe a ti rán on lati jẹ́ atọ́nà fún mi nínú ìrìn-àjò mi, Mo sì tẹ̀ lé e. Kí ni ohun mìíràn tí mo tún lè ṣe? Lẹ́hìn tí a ti rìn jìnnà díẹ̀, a ri oke ńláǹlà kan níwájú wa. Apá ibi tí o kọjú si wa lára òkè na si dúró gbọn-in gbọn-in, O dabi ìgbàtí a ti gé òkè náà si méjì ti a si gbé apákan kúrò. Lára ògiri yíì ni mo ti ri àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kà ketekete, ''Ọ̀run àpáàdì nìyí." Nígbà náà ni Ọ̀gbẹ́ni Atọ́nà mi yi sún mọ́ ọ ògiri ńláńlá yi, o si fi ọ̀kọ̀ ńláǹlà tí ọwọ́ rẹ̀ lùú lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Ilẹ̀kùn ńláǹlà kan sì ṣí sílẹ̀, a sì wọlé. Nígbà náà ni ó tún mú mi gba ti ibití ó dàbí ọ̀nà níbẹ̀, a sì wọ inú òkè ńláńlá yìí lọ.
Fún àkókò díẹ̀, a ń rìn nínú òkùnkùn biribiri tí ó dàbí irú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Égíptì. Ìró ẹṣẹ̀ atọ́nà mi ni mo ǹfetí sílẹ̀ sí, tí mo sì ńtẹ̀ lé e. Bí a ti ń lọ ní mo ńgbọ́ ìkérora ńláǹlà èyí tí àwọn ènìyàn ńké bíi ẹni pé nwọ́n ńkú lọ. Bí a sì ti ń tẹ̀síwájú sí í, ìkérora náà ńpọ̀ sii. Mo sì gbọ́ bí nwọ́n ṣe ńké fún omi, omi, omi. Bí a sì ti tún dé ibi Ilẹ̀kùn mìíràn tí a kọjá rẹ, igbe náà pọ̀ í, ó sì tó ti ẹgbẹgbẹ̀wá ènìyàn. Gbogbo wọn ni ó sì ńké omi, omi, omi. Láìpẹ́, atọ́nà mi tún kàn ilẹ̀kùn ńláǹlà kan èyí tí ó tún ṣí sílẹ̀. Mo sì ṣe àkíyèsí pé a ti kọjá òkè ńláńlá náà, àti pẹ̀lú pé pápá tí ó tẹ́jú ńláǹlà kan ni ó wà ní iwájú mi.
Níhìn-ín yìí ni atọ́nà mi ti fi mi sílẹ̀, ti o tún lọ tọ́ àwọn ènìyàn mìíràn ti nwọn ti sọnù lọ́nà wá sí ibi ibi àfonífojì yìí. Mo dúró nibẹ̀ fún àkókò díẹ̀ ki abàmì ẹ̀dá mìíràn ti o jọ ti ìṣáájú to tún tọ̀ mi wa; ṣùgbọ́n dípò ki o mú ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, idà ńláńlá kan ni o wa lọ́wọ́ rẹ̀. O wa láti wa sọ fún mi nípa ìyá àìnípẹ̀kun ati ègbé ti o wa fún mi ni ọjọ́ iwájú. O sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn ti o lè mu ìbẹ̀rù wọ inu ọkàn ènìyàn. Ó sọ pé, “Ọ̀run àpáàdì” ni ìwọ wa, nítorí náà ìwọ ko tún ni ìrètí kankan mọ́. Bi o ti ń kọjá láàárín òkè ńláǹlà ti o wa lọ́húǹ yi ki o to de ìhìn yí, o ngbọ́ bi àwọn ti o ti sọnù ti ń kérora ti ńwọn si ń ké fún omi láti fi pa òùngbẹ wọn. Láàrin ọ̀nà náà ti ìwọ gbá wa ni ilẹ̀kùn kan wà ti o lọ si inú Ọ̀run-àpáàdì —ibití yio jẹ́ òpin rẹ láláìpẹ yìí. Ṣùgbọ́n ki a tó mu ọ lọ si ibi ìdánilóró yìí, ní bìtì ìwọ kò ni ti ri àyè láti jáde mó — nítorípé ìrètí ko si fún àwọn ti o ba ibẹ̀—- a o fún ọ ni àyé láti dúró ni ibi tí ó tẹ́jú yìí fún ìgbà díẹ̀. Níhìn-ín ni a ti ń fi àwọn nkàn dáradára ti awọn ẹmí ti o ti sọnù ti pàdánù hàn fún wọn ki nwọn to lọ bẹ̀rẹ̀ si jìyà títí ayérayé.
Nwọ́n fi mi sílẹ̀ lọ pẹ̀lú ìrírí ti mo ti ri yìí. Bóyá àwọn nǹkan ti mo ti ri ni o mu mi di aláìníyè nínú mọ́ ni o, ko ye mi, Mo di aláìlágbára pátápátá. Ẹṣẹ̀ mi ko tún leè gbé ara mi dúró mọ́. Mo ṣubú lulẹ̀ bi aláìní olùrànlọ́wọ́. Orun si bẹ̀rẹ̀ si ń kún mi. Mo ń tòògbé, o si dàbí ẹni pé mo ńlá àlá. Lókè orí mi, lọ́nà jíjìn réré, mo ri ìlú ti o dára ti a ń sọ̀rọ̀ rẹ nínú Bíbélì. Báwo ni àwọn ògiri rẹ ti a fi òkúta jásípérì se ti l’ẹ́wà tó, ó si ti ya'ni l’ẹ́nu to! Ní ọ̀nà jíjìn réré lọ̀hún ni mo ti ri àfonífojì ti o kún fun àwọn òdòdó dáradára, ti o si l’ẹ́wa gidigidi. Mo ri odò omi ìyè àti dígí ti o pọ̀ bi omi òkun, Àwọn áńgẹ́lì si ń wọlé, ńwọ́n sí ń jáde lẹ́nu bodè ìlú náà. Ńwọ́n si ń kọrin bi ńwọ́n tí ńṣe bẹ́ẹ̀. A! báwo ni orin náà ti dùn to! Láàrin ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ni mo ti rí ìyá mi ọ̀wọ́n, eniti ko ti ju ọdún mélòó kan sẹ́hin ti o kú. Ìbànújẹ́ nítorí ìwà búburú ti mo ńwù ni o se pa ìyá mi náà, Ó wo apá ọ̀dọ̀ mi, o si dàbí ẹni pé o s'ẹ́wọ́ sí mi pé ki n máa bọ̀ wa sí ọ̀dọ̀ òun ṣùgbọ́n èyí kò leè ṣeé ṣe, O dàbí ẹni pé òṣùwọ̀n wúwo kan wúwo tẹ̀ mi mọ́lẹ̀. Ni àìpẹ́ afẹ́fẹ́ olóore kan gbé òórùn dídùn àwọn òdòdó dáradára ti o wa lọ́hún wa si apá ọ̀dọ̀, mo si ríran ri gbogbo nkàn kedere ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Gbọ́ ohun àwọn áńgẹ́li wọnnì bi o ti dùn tó. Mo sọ fún ara mi pé, 'Yio ti dun to, bí mo bá leè jẹ́ ọ̀kan nínú wọn’.
Bí mo ti nmu ninu ago dídùn yìí ni nwọn sa gba a bọ́ lẹ́nu mi lójijì. Mo jí kuro ninu orun mi. Mo, ti kuro ni ibi tí àlá dáradára náà gbé mi lọ, mo tun bọ́ si inú òkùnkùn biribiri ti tẹ́lẹ̀. Arákùnrin ti o ti fi mi sílẹ̀ si ti tún padà de, o si sọ fún mi pé o ti tó àkókò fún mi láti bọ́ sì inú ìgbé ayé titun. Ó sọ fún mi pé ki n máa tẹ̀lé òun. Mo padà sẹ́yìn, mo si tún wọ inú ọ̀nà ti o ṣókùnkùn náà lọ. Mo ń tẹ̀lé olùtọnà mi fun àkókò díẹ̀, nígbàtí a de ibi tí ọ̀nà kan tí ṣi silẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ti mba bọ̀, a tún bọ́ si ọ̀nà títún yìí. Bí a si ti ń gba ti ona yí lọ, a de ibi tí ọ̀nà mìíràn tún wà. Sì kíyèsí i, mo ńwo iná Ọ̀run-àpáàdì gan lókèèrè.
“Níwọ̀n bá ibi tí ojú mi leè ri lókèèrè, mo ri Ọrùn àpáàdì gan eyi ti o nfi iná ati súlfúrù jó. Báyìí ni iná ti ń tẹ̀lé ara won. Tí ìjì iná gẹ́gẹ́bí ti omi òkun ngun orí ara wọn gẹ́gẹ́bí ìgbàtí afẹ́fẹ́ líle ba n da mú omi òkun. Ninu ọ̀wọ́ iná ni mo ti nri ọmọ ènìyàn ti iná ń gbé wa s’òkè, ti o si tún ń gbé wọn lọ sí ìsàlẹ̀. Nígbàtí ìjì iná líle náà ba si tún gbe wọn wa sókè fún ìgbà kan, nwọn a tún bẹ̀rẹ̀ sí í bú Ọlọ́run, igbe won fun omi a si tun pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ti yio fi fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ ènìyàn lọ́kàn. Báyìí ni iná náà ati igbe àwọn ènìyàn ti o ti sọnù wọnyi ń dún lọ kánrin láìdúró rárá fún ìgbà kan.
"Laipe mo kọjá si ilẹ̀kùn ti a ba wọlé, mo si ka ohun ti a kọ síbẹ̀ ti o wi báyìí pe, "Òpin rẹ nìyí; ibi ègbé ayérayé." Láìpẹ́ ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si ya ẹnu rẹ lábẹ́ ẹṣẹ̀ mi, mo si ri pe mo ń rì si inú Ọ̀run àpáàdì. Òùngbẹ ti ko ṣeé fi ẹnu sọ si bẹ̀rẹ̀ sí ńgbẹ mi. Bi mo si ti ń ké pé, Omi, Omi, Omi, ojú mi ṣí, mo sì ba ara mi nínú ilé-oògùn àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
"Èmi kò tíì sọ ohun ti ojú mi ri yìí fún enikeni rí nítorípé ẹrú ḿbà mi bóyá àwọn olórí ẹlẹ́wọ̀n yio ronú pe orí mi yí, ki nwọn si ti mi mọ́le. Lẹ́yìn ìgbàtí gbogbo wọnyi ti ṣẹ si mi, o tẹ mi lọ́run ki nsa ti wa láàyè níwọ̀n ìgbà tí mo ti mọ̀ dájú pé Ọ̀run-àpáàdì wà dájúdájú irú èyí tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ rẹ ati pe Ọ̀run-rere wa pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ohun kan ti o da mi lójú ni pé, nkò ni tún dé Ọ̀run-àpáàdì mọ́ láéláé lai.
"Bi mo ti la ojú mi ninu ilé-oògùn, ti mo si ri pé mo wa láàyè, mo sì tún wa láyé, mo yára fi ọkàn mi fun Ọlọ́run lẹ́sẹ̀ kan náà, mo si mọ̀ dájú pe nínú ìgbé-ayé mi títí di ọjọ́ ikú mi, èmi ko ni tún kúrò ní ojú ọ̀nà ìgbàgbọ́ mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn nkàn búburú
tí mo ti ri nípa Ọ̀run-àpáàdì ko le kúrò ni ìrántí mi mọ́, bákannáà ni nkò tún lè gbàgbé àwọn nǹkan dáradára tí mo ti ri ni Ọ̀run rere. Emi yio lọ ba ìyá mi láìpẹ́. Nwọn yio fi àyè fún mi láti jókòó létí odò dídára náà. Láti máa wo àwọn òdòdó ti o lẹ́wà ju ohunkóhun ti ènìyàn leè rò lọ. A! F’etí si orin ti àwọn ti a ti rà padà ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́àgùntàn ńkọ́ - gbogbo wọ̀nyí ni yio mu ki n lè gbé ìgbé-ayé mi gẹ́gẹ́bí onígbàgbó tòótọ́ nígbàtí mo sì wa láyé, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé mo níláti kọ àwọn oríṣiríṣi ìgbádùn ti mo ti ń gbádùn ki n tó wa si inú ilé túbú yi sílè. Mo ti kọ àwọn ẹgbẹ́ arú'fin tí mo ti ḿbá k’ẹ́gbẹ́ silẹ̀. Emi yio si máa ba àwọn ẹni rere k’ẹ́gbẹ́ nígbàtí mo ba tún di òmìnira lẹ́ẹ̀kan sí i."
A sọ ìtàn yí gẹ́gẹ́bí a ti gbà á gan láti ọwọ́ Lennox.
Ọkàn nínú àwọn ẹÓ jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìrírí ti o ya ènìyàn l’ẹ́nu jùlọ nínú gbogbo àwọn ti a ti gbọ́ ri. Ki Ọlọ́run fi ìbùkún si ẹ̀kọ́ yíì ti o ti ọwọ́ Ọ̀gbẹ́ni Lennox wá, ki o si jẹ́kí ẹ̀kọ́ náà leè mu àwọn ẹ̀mí ti o ti sọnù wa si ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Báwo ni ènìyàn ti le máa ṣiyèméjì nípa Ọrùn-àpáàdì. A ń gbọ́ nípa rẹ̀ nígbà gbogbo a si ni ìdánilójú pé o wa ni tòótọ́. Ìwọ ọ̀rẹ́ mi, sọ fún mi bi nwọn ti lè sọ pé ko si Ọrùn-àpáàdì nígbàtí a rí i kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ti a si tún ń rí ìfihàn irú èyí tí o wa nínú ìwé yìí lati ìgbà dé ìgbà. Nítorí Ọlọ́run, ẹ̀yin ọkùnrin àti Obìnrin, ẹ dúró! Ẹ gba ìgbàlà àti ìyípadà ọkàn ti Ọlọ́run ti pèsè fún ń yín nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ Rẹ, kí ẹ ma bàa ri irú ìrírí yí tàbí èyí tí o burú ju èyí lọ, ti ki ìṣe fún wákàtí 48 ṣùgbọ́n fún ayé àìnípẹ̀kun ní Ọ̀run-àpáàdì.