Nípa

Àwùjọ Ìwé Ìléwọ́ Ìhìn-rere Àti Bíbélì ni a gbékalẹ̀ fún ìpín fúnni ọ̀rọ̀ ìgbàlà ọkàn tí ó ní àtìlẹyìn Bíbélì fún ènìyàn yíká-yíká àgbáyé. Ìfojúsùn wá dúró lórí ọ̀rọ̀ tí a tẹ̀, lílo àwọn ìwé ìléwọ́ ní ìrọ̀rùn. Àwọn ìwé ìléwọ́ wọ̀nyí ṣàlàyé kíni Bíbélì sọ fún wa nípa ìgbàlà, ìgbé ayé Jésù Krístì, àti gbígbé ìgbé ayé ti Krìstìẹ́nì. Àwọn ìwé ìléwọ́ wá wà nínú ẹ̀rọ ayélujára (wẹ́ẹ̀bù) wá fún kíkà, àti pẹ̀lú, púpọ̀ sì tún wà nínú tí alágbè kalẹ̀ ohùn (ọ́ọ́díò) wa. Ìgbékalẹ̀ ilé iṣẹ́ wa jẹ́ láti inú ìfẹ́ ìyọ̀nda-ara-ẹni pẹ̀lú ìran láti tọ́ka olúkúlùkù ènìyàn sí ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Krístì. A ní àwọn òjíṣẹ́-Ọlọ́run tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìrànwọ́ nípa títẹ̀ àti pípín àwọn ìwé ìléwọ́ wọ̀nyí lọ́fẹ̀ ní Àríwá Ilẹ̀ Ámẹ́ríkà, Gúúsù Ilẹ̀ Ámẹ́ríkà, Ilẹ̀ Áfríkà, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Asia. Nwọ́n sí tún máa ń lọ sọ́dọ̀ tí wọ́n ti Kọ̀wé sí wa tẹ́lẹ̀ tí ń fẹ́ àlàyé fún ìbéèrè wọn. A ní Olú Ilé Iṣẹ́ méjì, ọ̀kan ní Ìlú Kansas, USA, èkejì sì wà ní Ìlú Manitoba, Canada. Àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyí ní ḿbójútó ìbánisọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, ṣíṣe kíkó-jọ-pọ̀ àti fífi àwọn ìwé ìléwọ́ wọ̀nyí rànsẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ wa ni ìbání-sọ̀rọ̀-pọ̀ tó péye pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní onírúurú èdè, Tí wọ́n sì ńṣe àmújútó gbogbo ìpè ìjà tí títẹ̀ àti kíkó jáde àwọn ìwé ìléwọ́ wọ̀nyí ń dojú kọ lásìkò lásìkò lágbàáyé. Àwọn ìwé ìléwọ́ wa ni àwọn àkòrí wọ̀nyí bíi Ìgbé Ayé Krìstíẹ́nì, Jésù, Àwọn ohun tí ṣe ìwà rere, Àlàáfíà, Ìgbé Ayé Ìdílé, Ẹ̀ṣẹ̀, àti ti Ọjọ́ Ọ̀la/Ọjọ́ Iwájú. A sì tún fún ní lílé ni Ọgọ́rùn-ún (100+) ìwé ìléwọ́ wọ̀nyí ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì, púpọ̀ nínú èyí tí a ti ṣe ìtumọ̀ wọ́n sí onírúurú èdè ọgọ́rin (80).