Ìgbàlà
Jesu sọ fun wa pe awọn ilẹkun ogo ti mọ wa, afi bi aba tun wa bi. Nitorina a bere lọwọ rẹ: ọrẹ, njẹ a ti tun ọ bi? Iwọ ọmọ Ijọ, njẹ a ti tun ọ bi? Bi bẹkọ iwọ ti sọnu. Nitori Jesu wipe, “Bikosepe a tun enia bi on ko le ri ijọba Ọlọrun” Johannu 3:3. Dajudaju ko si ẹniti o fẹ ku sinu ẹsẹ tabi ti o fẹ segbe; nitorina, a nilati tun ọ bi.
Eyi jẹ ibere ti o dara pupọ ti o yẹ ki olukuluku enia bere. O jẹ nipa opin ẹmi enia ni ibugbe aiyeraiye–aiye ainipẹkun. Bi iwọ ko ba se onigbagbọ, iwọ ko iti di atunbi. Jesu sọ wipe, “–A ko le se alaitun nyin bi.” Johannu 3:7. O jẹ atunbi–iriri itunnibi. Lọrọ kan, o jẹ yiyi ni lọkan pada, “ki a le pa ẹsẹ nyin rẹ,” Ise Awọn Aposteli 3:19