Eyi jẹ ibere ti o dara pupọ ti o yẹ ki olukuluku enia bere. O jẹ nipa opin ẹmi enia ni ibugbe aiyeraiye–aiye ainipẹkun. Bi iwọ ko ba se onigbagbọ, iwọ ko iti di atunbi. Jesu sọ wipe, “–A ko le se alaitun nyin bi.” Johannu 3:7.
Kini a npe ni “Atunbi”?
O jẹ atunbi–iriri itunnibi. Lọrọ kan, o jẹ yiyi ni lọkan pada, “ki a le pa ẹsẹ nyin rẹ,” Ise Awọn Aposteli 3:19
Tani o nilati ni Atunbi yi?
Olukuluku ọkunrin ati obinrin ati olu- kuluku ọdọ-mọbinrin ati ọdọ-mọkurin ti ọjọ ori rẹ ti de ipo imọ ati oye ni anilati bi nipa ti ẹmi. Ninu ori 53 woli Isaiah, bi o ti wa ninu Ẹmi Mimọ fi aworan ijiya Jesu Oluwa fun ẹsẹ awa enia han ni ọpọlọpọ ọdun saju akoko ni. Ninu ẹsẹ kẹfa o sọ bayi pe, “Gbogbo wa ti sina kirikiri bi aguntan; olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ, – “Jesu mu ki o ye Nikodemu olukọni ni Israeli kedere nigbati başepe atun enia bi, on ko le ri ijọba Ọlọrun.” (Johannu 3:3). O si sọ fun pẹlu pe atunbi nipa ti ẹmi ni. Oludari eyi ni Ẹmi Mimọ.
Jesu npe “Ẹ wa sọdọ mi, gbogbo ẹnyin ti nsisẹ, ti a si di ẹru wiwo le lori, Emi o si fi isimi fun nyin, ki ẹ ma kọ ẹkọ lọdọ mi: nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkan nyin. Nitori ajaga mi rọrun, ẹru mi si fuyẹ” (Matteu 11:28-30). Gbogbo awọn ti aisan ati ti ẹru ẹsẹ wọn npa ni a npe ki wọn wa lati sọọ kalẹ li ẹsẹ agbelebu Jesu, ki nwọn si “gba ilaja” (Romu 5:11). Jesu jiya, O ta ẹjẹ Rẹ silẹ O si ku lori igi agbelebu. “Etutu (etutu iku ti ara Rẹ) fun ẹsẹ wa: ki ise fun tiwa nikan, sugbọn fun gbogbo araiye pẹlu” (I Johannu 2:2). Awa nilati mọ ẹbi ẹsẹ awọn ẹsẹ wa lara – ati pe Jesu gba iya irora jẹ ni ipo wa. “Ẹniti o bo ẹsẹ rẹ mọlẹ ki yio se rere: sugbọn ẹnikẹni ti o jẹwo to o si kọ ọ silẹ yio ri anu.” (Owe 28:13). Bi o ti wu ki ẹsẹ enia ti tobi to, ireti mbẹ fun ọ. “Wa nisisiyi, ki ẹ si jẹki a sọ asọye pọ: bi ẹsẹ nyin ba ri bi ododo wọn o si fun bi ojo didi; bi wọn pọn bi alari, wọn o dabi irun–aguntan” (Isaiah 1:18). “–Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ asọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu Ẹjẹ Ọdọ-aguntan ti Jesu Kristi” (Ifihan 7:14).
“Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwo Jesu ni Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkan rẹ pe Ọlọrun ji I dide kuro ninu oku, a o gba ọ la” (Romu 10:9). Gbigbagbọ ati si sẹ Igbagbọ ati Isẹ, ba ara wọn lọ li ọna kanna. “Kiyesi, mo duro li ẹnu ilẹkun, (Ilẹkun ọkan na) mo si nkan-kun (npe), bi ẹnikẹni ba gbọ ohun mi, ti o si şi ilẹkun (awa nilati dahun ipe rẹ ki a si şi ilẹkun ọkan wa), emi o si wọle tọ ọ wa, emi o si ma ba jẹun (igba idapọ didun), ati on pẹlu mi.” (Ifihan 3:20). Iru ogo ati igbadun wo lo to bayi bi pe ki a ri idariji awọn ẹsẹ wa gba ati “alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (Romu 5:1). O jẹ ibẹrẹ ọrun-rere lati aiye lọ. “Nitorina bi ẹnikẹni ba wa ninu Kristi o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ: kiyesi nwọn si di titun” (II Kọrinti 5:17). “Njẹ ebi ko si nisisiyi fun awọn ti o wa ninu Kristi Jesu, awọn ti ko rin nipa ti ara bikosi nipa ti Ẹmi.” (Romu 8:1). Ifẹkufẹ ti ara ati ifẹkufẹ oju ati irera aiye (I Johannu 2:15-17) ati isẹ ara gẹgẹbi ati darukọ wọn ninu Galatia 5:19-22, wa lode ile-igbala. Nigbati o jẹ pe awọn eso ti Ẹmi gẹgẹbi a ti kaa ni Galatia 5:22-26; kun fun “ileri ti aiye isisiyi ati eyi ti mbọ” (I Timoteu 4:8).