Ọjọ ti mo ri ofifo apo-iwẹ gba lati ọdọ ẹgbọn Baba mi ni mo mọ riri iwẹ gbigba lati okeere. Adirẹsi ti mbẹ lẹhin apo–we na pe perepere, Iye owo to a fi nfi iwe ransẹ ni a si san fun, sugbọn ko si ohun kan ninu apo – iwe na.
Gbogbo wa ni a ma nri iwe gba lati igba – de igba bẹni a ko nani iru ẹkọ ti ẸMI ti a le kọ ninu awọn iwe wọnyi.
Ki a to mu iwe lo si ile ifiwe ransẹ (Post Office), lẹhin ohun–elo ikọwe, ani lati ni apo–iwe ati owo ti o to fun fifi iwe ransẹ lọwọ.
Lehin eyi ni ao bẹrẹ si kọ iwe si ẹni na ti a fẹ kọ iwe si. Nigbati a ba kọ tan, ao fi sinu apo – iwe, ao lọ ju sinu iho ibiti ati nfi Iwe ransẹ, nibiti awọn osisẹ ile – ifi iwe iransẹ yio ti ri pe o bẹrẹ irin ajo rẹ laipẹ. Ami ifi iwe ransẹ ti mbẹ lẹhin apo iwe na ni wọn o fi ontẹ lu, ki o ma ba wulo fun ẹlomiran. Apo iwe ati ami ifiwe ransẹ na ni yio jẹki o tẹ ẹniti oni lọwọ. Ẹniti inu rẹ dun lati ri iwe gba. Ko jafara rara lati ja apo iwe na, O le ya, ge tabi ki o fi suru ja apo iwe na (eyikeyi ti o ba fẹ) lati tete ri ohun ti mbẹ ninu iwena. Apo ti o gbe iwe na wa ni (envelope) ati ami ifiwe ransẹ (Stamp) ni ao run, ti ao si sọ sinu agbọn idọti, nibẹ ni irin ajo rẹ si pari si. Sugbọn iwe ti mbẹ ninu rẹ ni ao wa akoko ati ibikan to o dara lati ka awọn ọrọ inu rẹ.
Eyiyi gan ni ohun ti a jẹ (LẸTA) iwe to a kọ ransẹ si aiye lati ọdọ Ọlọrun ninu apo – iwe t’ise ara wa. Ti anse lọsọ orisirisi gẹgẹbi ami ifi – iwe ransẹ (Stamp) an fun ara na ni gbogbo ami ifi iwe ransẹ ti oyẹ fun irin ajo si ọna jijin tabi nitosi lati se awari iba kẹgbẹ isuna, imọ ati ibarẹ aiye yi.
Eyi ni a nse tobẹ gẹ ẹ ti a fi gbagbe pe ohun kan soso ti o se iyebiye julọ ninu ara wa ni ỌKAN WA.
Ni kukuru a o de ọwọ eniti yio gba wa eyini ni IKU ẹniti yio sọ gbogbo agbara ati iwa wa di asan nipa jiju wa sinu agbọn idọti ti ara ti ise ISA-OKU. Eyi ni IKU nse lẹhin igbati o ba ti ba ara wa jẹ tan ninu jamba moto, isẹlẹ ibi, nipa aisan tabi ọna miran lati yẹ Iwe eyiti ise ọkan wa wo. Lẹhin eyi ni yio fi sọwọ ẹniti oni iwe na, Ọlọrun Alagbara. Ẹniti yio ka iwe na lati ri ohun ti mbẹ ninu rẹ. Igbe aiye rẹ le salai sofo (bi oti ri loju rẹ) Iwọ tile lọwọ ninu ọpọ ohun ti imu igbe – aiye dun. Nigba miran o ti le kọ ipe ọrẹ rẹ pẹlu ọrọ yi pe “Emi ko ri aye, nitorina yọnda fun mi” Sugbọn Ọlọrun mọ pe irọ gbaa ni a pa, pe iwọ ko se nkankan.
Ni ikẹhin nigbati ao gbe ibere aiyeraye na ka iwaju rẹ pe: Kini iwọ tise nipa Ẹjẹ Jesu? Iwọ yio fẹ pada lati lọ tun ọna rẹ se, nigbayi ni iwọ yio ranti pe “ati fi Ontẹ lu ami ifiwe ransẹ ati pe atunse kosi mọ” Nigbati iwọ ba farahan niwaju onidajọ ti o wipe “Ẹlọ kuro lọdọ mi, ẹyin ẹni egun sinu ina ainipẹkun ti a ti pese silẹ fun Esu ati awọn angẹli rẹ” (Matt. 25:41) Iwọ yio bẹbẹ fun aanu sugbọn yio ti PEJU.
Ohun to iwọ yio tun gbọ nipe: “Wo o, nigbati ẹmi rẹ si mbẹ iwọ ko lo fun Ogo Ọlọrun, melomelo ni igbati o wa bọ sinu ina ajooku tan, njẹ o wulo fun Ọlọrun mọ? Nigbati iwọ ba dajokọ Itẹ Idajọ nigbana ni iwọ yio mọ riri iru igbe aiye ti o ti lo.
A! Iwọ Olukawe mi, bi o ti nronu nipa nkan wọnyi, kini se ti iwọ ko kuku fi ọkan rẹ fun Kristi, ẹniti o wipe “Ẹniti o ba si tọ mi wa, emi ki yio ta nu, bi oti wu ko ri” (John 6:37b) Kini se ti iwọ ko kuku gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala rẹ ki ọkan rẹ tise iwe na to de ọwọ Re. Ranti pe Ọlọrun ran Ọmọ bibi Rẹ nikan soso wa si aiye yi kise lati da araiye lẹjọ sugbon ki a le ti ipasẹ re gba araiye la” (Johannu 3:17). Anfani wo ni o jẹ fun ọ lati ma se Apo–Iwe na lọsọ (iyẹn ara rẹ) pẹlu gbogbo agbara rẹ ki o si wa ri pe ni opin irin ajo rẹ pe iwe na (Eyi ti ise ọkan rẹ) ni eniti yio gba apo iwe na kasi julọ: “Nitori eruppẹ sa ni iwọ, erupẹ ni iwọ yio si pada si.” (Gen. 3:19).
Jẹwọ fun Kristi iru igbesi aiye ti ko nilari ti o ti ngbe bọ ki o si gba A gẹgẹ bi ẹniti oni ọkan rẹ ki iwe rẹ (Eyi ni akọsilẹ nipa igbe – aiye rẹ) to tẹ ẹ lọwọ lati ọdọ IKU, eyiti yio mu ọ ba Ọlọrun dojokoju. Nje iwọ yio se eyi bi? Se be ẹ loni. ONI GAN NI ỌJỌ ITẸWỌGBA. ILE ỌLA LE MỌ BA Ọ NIWAJU ITẸ IDAJỌ TI ỌLỌRUN!