Gbogbo agbaye lo kun fun iwuwa ẹsẹ. A ti jogun isẹda imọtaraẹninikan, aiwa bi Ọlọrun ti o yawa nipa si Ọlọrun. O jẹ pataki fun wa lati se idamọ ẹsẹ dida wa ki a si kaanu fun awọn ẹsẹ ti a ti da.
Iran eniyan ni ibasepọ ti o rẹwa tẹlẹ pẹlu Ọlọrun. Nipa aigbọran Adamu ati Eefa ninu ọgba Edẹẹni ẹsẹ wọ aye. (Gẹnẹsis Ori 3). Eleyi lo ya wọn nipa si Ọlọrun bi iwe mimọ ti kọni: “Nitori gẹgẹ bi ẹsẹ ti ti ipa ọdọ eniyan kan wọ aye, ati iku nipa ẹsẹ; bẹẹni iku si kọja sori eeyan gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo eniyan ti dẹsẹ:” (Rom. 5:12).
Ọlọrun fẹ ni ibasepọ to l’ẹwa pẹlu gbogbo eniyan, sugbọn ki ise pẹlu awọn ti ngbe ninu ẹsẹ. Gbogbo eniyan “ti sẹ, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun” (Rom. 3:23).
Bi eniyan ba kọ lati ronupiwada kuro ninu ẹsẹ, o jẹbi iyanipa ayeraye kuro lọdọ Ọlọrun sinu ọgbun ainisalẹ ti ọrun apaadi. Ọrun apaadi jẹ bi ti a ti pese silẹ fun esu ati awọn angẹli rẹ pẹlu gbogbo awọn to tẹlee lẹyin. Ọlọrun ko fẹ ki ẹnikan segbe sugbọn ki gbogbo eniyan lee ye. (2 Peteru 3:9).
O fi ifẹ rẹ ti o tayọ han si gbogbo eniyan nipa riran Jesu, Ọmọ rẹ kan soso, lati ku lori agbelebu fun awọn eniyan ẹlẹsẹ (Johannu 3:14-20). Jesu san gbese ẹsẹ wa nipa fifi ẹmi ara Rẹ lelẹ ti o si ta ẹjẹ Rẹ silẹ. Oore-ọfẹ Ọlọrun ni eyi fun iran eniyan.
Ọlọrun jẹ Ọlọrun onifẹ ti o ga. Wipe O tilẹ ronu ati se eto fun irapada iran eniyan, jẹ amin ifẹ ijinlẹ ati aanu ti ko see f’ẹnu sọ. Sisi’lẹkun silẹ fun ironupiwada si igbala jẹ isẹ ifẹ bi o tilẹ jẹ wipe ironupiwada jẹ iriri ti o nira fun eniyan.
Ki eniyan to kun fun ẹsẹ to le jẹ ninu anfaani oore-ọfẹ yii, ogbọdọ mura tan fun awọn gbedeke ti ọrọ Ọlọrun, Bibeli ti la silẹ. Eniyan, nipa ifẹ inu ara rẹ ko lee ronupiwada, tabi gba idande lọwọ ẹsẹ ayafi ti Ọlọrun ba faa wa sọdọ Jesu (Johannu 6:44). Nigbati awọn eniyan ninu ẹsẹ ba gba idalẹbi ẹsẹ lati ọdọ Ẹmi Mimọ, ifarahan oore-ọfẹ Ọlọrun ni eyi.
Ọlọrun ran Johannu Bamutiisi lati waasu ironupiwada si awọn araye ti nsegbe. Ọrọ iwaasu rẹ ni: “Ẹ ronupiwada nitori ijọba ọrun ku si dẹdẹ” (ẹ ka Matt. 3:1-12). Jesu waasu ohun kannaa nigbati O de. Ironupiwada jẹ nini abamọ ati irobanujẹ ti o jinlẹ fun ẹsẹ ati awọn isẹ ẹsẹ ti eeyan ti se. Olukuluku eniyan lo gbọdọ wa si ipo irobinujẹ yii, ko si mọ pe ẹlẹsẹ ni oun ati pe ẹsẹ nda eniyan lẹbi ọrun apaadi. Ko si ẹsẹ tabi ẹlẹsẹ kan to le wọ ọrun nibiti Ọlọrun ngbe.
Nigbati Johannu Bamutiisi nse iwasu rẹ ti o ye kooro tio si rẹlẹ (Wo Luku 3:1-18), awọn ti o gbọ ọ ni idaamu ti o jinlẹ. Eleyi ni idalẹbi ọkan fun ẹsẹ. Ohun kannaa ni o sẹlẹ nigbati Peteru ati awon yoku nwasu ni ọjọ Pẹntikọsti (Isẹ Awọn Aposteli 2:37-40). (Fun apẹẹrẹ miran ka iwe Jonah 3). Asiri ẹsẹ awọn eniyan wọnyi tu nipa iwaasu ọrọ Ọlọrun. Ẹmi Mimọ da wọn lẹbi lati jẹ ki nwọn mọ pe awọn segbe, labẹ iparun ina ayeraye ninu ọrun apaadi. Nigbati awọn onidaamu ọkan yi beere ohun ti wọn yoo se, wọn sọ fun wọn pe ki wọn ronupiwada. Nwọn nilo lati kaanu fun igbe aye ẹsẹ wọn, ki wọn si tun yipada kuro ninu ẹsẹ ati iwa ibi.
Ironupiwada, gẹgẹ bi Bibeli ti kọ ni, ki ise atunse bẹẹ. Nigbati Ọlọrun ba fi ipo ẹsẹ ọkan wa han fun wa, a mu abamọ wa fun awọn ẹsẹ ati ohun wọnni ti a ti se sẹyin. Omije ikaanu ọkan maa nlọ papọ nitoriti ẹni naa ni imọlara wipe ẹlẹsẹ ni oun jẹ. O si ri iru ibanujẹ to mu ba Ọlọrun ti awọn eniyan ẹlẹgbẹ rẹ.
Ko si agabagebe ninu ironupiwada otitọ. Ironupiwada ki ise ohun ti a nse lati tẹ eniyan lọrun. O jẹ igbogun ti ẹsẹ lotitọ niwaju Ọlọrun mimọ. “Nitoripe ibanujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun a maa sisẹ ironupiwada si igbala ti ki mu abamọ wa: sugbọn ibanujẹ ti aye a ma sisẹ iku. Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni iwa-bi-Ọlọrun, isọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti to, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ ninu ọran na.” (2 Korinti 7:10-11).
Ẹkunrẹrẹ alaye lori ironupiwada wa ninu itan ọmọ oninakuna ninu iwe Luku 15:11-21. Ọlọtẹ ọmọ yi ri ara rẹ ninu idalẹbi ọkan nigbati o wa loko ẹlẹdẹ. O ti fi igbe aye ati owo rẹ sofo. Igbayi lo to mọ pe oun ti kọkọ dẹsẹ si Ọlọrun ati pẹlu si baba rẹ. O baa ninu je tobẹẹ to fi ri i pe oun ko yẹ rara fun anfaani ipo ọmọ. O setan lati se gẹgẹ bi alagbase baba rẹ, bi oun o baa le ni ounjẹ ajeyo ati ibugbe to mooru lati sun. Nigbati o ri baba rẹ, o jẹwọ awọn ẹsẹ rẹ, baba rẹ si fi tayọtayọ darijii. Bakanna, Ọlọrun setan, tinutinu lati dariji ẹlẹsẹ to runupiwada. Akọsilẹ miran ninu iwe Luku 19:1-10 sọ fun wa bi ọlọrọ agbowo-ode, Sakeu, ti o nwa Jesu. Ara rẹ ko balẹ nitori igbe aye ẹsẹ rẹ. Nigbati Jesu de ile rẹ o ironupiwada. Ninu irobinujẹ ọkan rẹ o yipada kuro ninu iwa rẹ atijọ, o se idapada awọn owo ti o fi eke gba. Ironupiwada rẹ jẹ ki o ri iwa wọbia rẹ. Ọkan rẹ yipada kuro ninu kiko ọrọ jọ si aanu awọn eniyan rẹ, nitorinaa o fi aabọ ohun ti o ni fun awọn alaini. Lọjọ naa ni Sakeu ri idariji ati igbala. Idahun jẹ eso ironupiwada. Johannu Bamutiisi pe iru idahun yii ni “eso ti o yẹ fun ironupiwada.” (Matt. 3:8).
Gẹgẹ bi awọn eniyan ba se nronupiwada ẹsẹ wọn, awọn eso kan ni yio fi han gbangba pe ironupiwada wọn jẹ otitọ/ojulowo. Nigbati alaisootọ eniyan ba ronupiwada, ti wọn si jẹwọ ẹsẹ wọn fun Ọlọrun ati eniyan, ti ole da ohun ti o ji pada (titi de ipo yiyọnda fun ijiya), nigbati ọmuti ri igbe aye buburu ti oun ti gbe ba kọ ọti mimu silẹ - eyi ni ironupiwada ẹni iwa-bi-Ọlọrun. Nigbati ẹni irira ri pe awọn ti sẹ si agọ ara awọn papaa ati gbogbo awọn ti wọn sọ di ẹni irira, nigbati ija ati irunu tabi ibinu ti o maa nsẹlẹ ninu idile di ẹsẹ titi de ipo ti wọn ko ja mọ-ironupiwada ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni eyi pẹlu.
Ori 11 ati 12 ninu Iwe 2 Samuẹli se akọsilẹ oun to sẹlẹ nigbati Ọba Dafidi ba Batsẹba se agbere pọ. Lati bo ẹsẹ rẹ mọlẹ o fi ọkọ rẹ to jẹ ologun si iwaju ogun ki a le pa. Bi a tilẹ le mu eniyan ni omugọ, ki işe bi ti Ọlọrun. Ọlọrun fi işẹ ran Natanieli woli si Dafidi. Nigbati Dafidi moye bi ohun ti oun se ti buru to, o gba ẹsẹ rẹ o si ronupiwada. Ka adura ironupiwada rẹ ninu iwe Orin Dafidi 51.
Ẹmi to ronupiwada yio kun fun irobinujẹ ati irora aya. Lati de ipo yi eniyan ni lati tọ Ọlọrun wa, jẹwọ awọn ẹsẹ rẹ. Ninu igbagbọ, eniyan a ma wo Jesu ati ẹjẹ rẹ ti o ta silẹ fun ẹsẹ rẹ. Nipa bẹẹ a si gba imukuro ẹsẹ ati alaafia pẹlu Ọlọrun a si di ẹni titun ninu Kristi (1 Johannu 1:5-10; 2 Korinti 5:17). Nigbati eyi ba ti sẹlẹ bẹẹ, ẹni naa yio, bi ti ọmọ oninakuna ati Sakeu, yio safẹri lati maa rin ni ọna Ọlọrun, ni sisin dipo ifẹkufẹ ara ati inu. Yio maa yẹra fun ibi ẹsẹ gbogbo ati awọn eniyan ti o tun lee mu pada sinu igbe aye ẹsẹ ti atijọ. Gbogbo awọn dukia to lodi si ifẹ Ọlọrun li o parun lati ma jẹ idekun ni ọjọ ọla (Işe Awọn Aposteli 19:17-20). Dipo eyi, a maa nifẹ lati ma ka Bibeli ki o si mọ ifẹ Ọlọrun, ifẹ inu lati ma gbadura nipa bẹẹ, a si ma ba Ọlọrun sọrọ pọ, ipongbẹ lilọ si ile ijọsin (Sọọsi) fun idapọ pẹlu awọn ti o ni iriri ironupiwada ati ti ibi tuntun.
Akojọpọ abajade gbogbo eyi ni idaniloju jẹẹjẹẹ ati alaafia ọkan ti o ju imọ gbogbo lọ (Isaiah 32:17; Filipi 4:7). Nigbayi ni eniyan fọwọsọya lati gba ileri ile ayeraye ni ọrun pẹlu gbogbo awọn ẹni irapada.