“Tani ó ni òsì? Tani ó ni ìbànújẹ́? Tani ó ni
Ìjà? Tani ó ni asọ̀? Tani ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?
Tani ó ni ojú pípọ́n? Àwọn tí ó dúró pẹ́ nìdí
ọtí-wáìnì; Àwọn tí ńlọ ídán Ọtí-wáìnì àdàlù wò. Ìwọ máse wo ọtí wáìnì pé ó pọ́n, nígbàtí ó bá fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a ń gbé e mì tí ó ń dùn. Níkẹyìn òn a bunisán bí ejò, a sì buniję bí paramọ́lẹ̀'” Òwe 23:29-32.
Báwo ni ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí ti fi àwòrán olùfẹ́ ọtí-wáìnì àti ọtí líle hàn wá tó! Gbogbo nkàn tí a rí kà nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n náà nípa àwọn ọ̀mùtí ni; ìbànújẹ́, ègbé, ìjà, ọ̀rọ̀ wèrè, ọgbẹ́, ojú pípọ́n. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni tí àwọn ènìyàn mb’ọ́lá fún ti di ęni àbùkù
àti ęni ìtẹ̀mọ́lẹ̀. Ọtí mímú ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aluni, jàgùdà àti apànìyàn . Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mùtí náà sì ti mú ìtìjú bá ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí nwọn dúró níwájú pẹpẹ láti ṣe ìgbéyàwó ronú pé ń wọn bá ọkọ rere pàdé, ẹni tí yíò fẹ́ràn wọn, tí yíò sì jẹ́ olùrànlọ́wọ́ òdodo, ẹni tí nwọ́n le è gbẹ́kẹ̀lé. A! báwo ni ó ti jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn tó lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí nwọn wá rí i pé ọkùnrin tí ń wọn fẹ́ kó ná owó ti ó fi òógùn ojú rę gbà lórí oúnjẹ bí kò ṣe lórí ọtí ati lórí tẹ́tẹ́, nwọ́n sọnù sínú ẹ̀ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni kí yíò si oúnjẹ àti asọ fùn ìyàwó ati àwọn ọmọ.
Nípa báyìí nwọ́n a si tún lé wọn sita kúrò nínú ilé tí nwọ́n ńgbe.
Ìwé Hóṣéà 4:11 sọ báyìí pé “Àgbèrè àti ọtí-wáìnì, àti ọtí wáìnì titun a máa gbé ènìyàn li ọkàn.” Àwọn tí wọ́n fi ara wọn fún ọtí mímú ni ń di ẹlẹ́sẹ, ọlọ́kàn líle. Nígbà tí nwọ́n bá sì ti mu ọtí tán, nwọn kì yíò tún rántí ọgbẹ́ tí ó wà lára won mọ́. Bẹ́ẹ̀ni nwọ́n ti gbàgbé àwọn ọgbẹ́ ati ìṣẹ́ ibi tí ń wọn ti dá sára àwọn ẹlòmíràn. Àwọn díẹ̀ rò pé ń wọn leè ṣẹ́ ara wọn láì mu ọtí púpọ gẹ́gẹ́bí ti àwọn ọ̀mùtí. Ṣùgbọ́n ki àwọn wọ̀nyí tó mọ ara wọn ní ọ̀mọútí, nwọn yíò ti lọ jìnnà nínú ọtí mímú. Ọ̀nà kan soso ti a leè fi bọ́ nínú ìgbèkùn ọtí ni kí a yàgò fún u pátápátá -kí a má tilẹ̀ fi ẹnu kàn án ní àkókò tí ń wọn fi lọ̀ wá.
Ó sàn jù kí a má ṣe lọ si ilé ọtí rárá. Ilé ọtí ń ti ilẹ̀kùn ọ̀run rere mọ́ ènìyàn. Àwọn ọ̀mùtí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. (I Kọ́ríńtì 6:10). “Kí a má ṣe tán yín jẹ; a kò leè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn oun ni yíò sì ká. Nítorí ęni tí o ba ńfúnrúgbìn sìpa ti ara rẹ̀, nípa ti ara ni yíò ká ìdibàjẹ́: ṣùgbọ́n ęni tí ó bá ńfúnrúgbìn sì ipa ti ẹ̀mí, nípa ti ẹ̀mí ni yíò ka ìyè àìnípẹ̀kun.” (Gálátíà 6:7-8).
Ilé ibití a ti ń tà ọtí-líle ni a máa ń pè ní ILÉ-ỌTÍ.
Ilé-ọtí jẹ́ ìdènà fún ọ̀run rere: ilẹ̀kùn ọ̀nà sí ọ̀run àpáàdì.
Ẹnìkẹ́ni ti o bá pè é ní orúkọ rẹ̀ kò ṣìnà rárá.
ÌDÈNÀ fún ìwà rere àti ọrọ̀;
Ilẹ̀kùn ọ̀nà si àìní àti àìlera.
ÌDÈNÀ fún iyì, ìgbéga àti òkìkí; Ẹnu ọ̀nà ìbànújẹ́, ẹ̀sẹ̀ àti ìtìjú.
ÌDÈNÀ fún ìdílé rere; ìdènà fún àdúrà ;
Ẹnu ọ̀nà sí òkùnkùn àti àìní retí.
ÌDÈNÀ fún ìgbé-ayé tí o lógo àti èyí tí kò wúlò;
Ẹnu ọ̀nà sí asọ̀ àti ìjà.
ÌDÈNÀ fún ohun gbogbo tí ìṣe òtítọ́ àti ìgboyà;
Ẹnu ọ̀nà ibojì àwọn ọ̀mùtí.
ÌDÈNÀ ayọ̀ ti ìdílé rere ń fún ni; Ẹnu ọ̀nà sí ẹkún àti ọkàn ìbànújẹ́.
ÌDÈNÀ ọ̀run rere; ẹnu ọ̀nà sí ọ̀run àpáàdì; Ẹnìkẹ́ni ti o bá pè é ní orúkọ rẹ kò ṣìnà rárá.
Ẹlẹ́yà ni ọtí-wáìnì, aláriwo li ọtí líle: ẹnìkẹ́ni tí a bá fi tán jẹ kò gbọ́n, Òwe 20:1. Nítorípé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yíò di tálákà; ọ̀lẹ ni yíò si fi àkísà bo ara rẹ̀, Òwe 23:21.
Ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú ti ipa ọtí-wáìnì ṣìnà, àti nípa ọtí líle nwọn ṣáko:- ọtí wáìnì ti gbé wọn mì, nwọ́n di asáko nípa ọtí líle, nwọn ṣìnà nínú ìran, nwọn kọsẹ̀ ni ìdájọ́. Nítorí gbogbo tábìlì li o kún fún èébì àti ẹ̀gbin, kò sí ibi ti o mọ́. Isaiah 28:7-8.
Jí, ẹyín ọ̀mùtí, ẹ si sọkún: si hu, gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí wáìnì. Joeli 1:5.
Ọ̀rẹ̀ mi ọ̀wọ́n: àbí ọtí mímu ti mú ọ ní ìgbèkùn? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ti ronú nípa ikú bí-ikú òjìji; àti ibití ìwọ yíò ti lo àìnípẹ̀kun? Ikú a pa ènìyàn níbi gbogbo-ó dúró lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ, gé-búburú rẹ ati àwọn ohun mìíràn tí ó wà nínú ìgbé-ayé rẹ tí ko tẹ́ Jésù Krístì lọ́rùn. Jésù kú lórí àgbélébùú, Ó ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ fún ìràpadà ẹlẹ́ṣẹ̀ tí o tóbi jùlọ, láti mú u padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ronúpìwàdà fún ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí o sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá. Ìwọ kò leè gba ara rę kúrò lọ́wọ́ ìwà búburú ti ọtí mímu nípa agbára ara à rẹ nìkan, bę Jésù láti wá rán ọ lọ́wọ́, Jésù múra tán láti se bẹ́ẹ̀ bí o bá wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, Jésù wípé, “a níláti tún ọ bí” (Jòhánù 3:7). Yíò dárí jì ọ, yíò sì fún ọ ní ọkàn titun. “Ṣùgbọ́n iye àwọn ti o gbà Á(Jésù), àwọn li a fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run , àní àwọn náà ti ó gba orúkọ Rẹ̀ gbọ́.”(Jòhánù1:12).